Àkànlò èdè áyàwòrán

E̩wà èdè ni àkànlò èdè jé̩ nis̩e ni àkànlò èdè máa ń ya àwòran sí o̩kàn e̩ni tí ó bá gbo̩ sétí tàbí tí ó bá kà á nínú ìwé. Ìtumò̩ méjì ni àkànlò èdè máa ń ní: Ìtumò̩ eréfèé àti Ìtumò̩ ìjìnlè.


Ajíbóyè (2002:57) s̩e àpèjúwe àkànlò – èdè ayàwòrán gé̩gé̩ bíi àwo̩n hóró ò̩rò̩, àpólà tàbí gbólóhùn tí as̩afò̩ lò láti mú adùn èdè wo̩nú afò̩ rè̩.  Ajiboye (2002: 58 – 91) la àwo̩n àkànlò èdè ayàwòrán tó wó̩pò̩ nínú lítírés̩ò̩ alohùn Yorùbá sílè̩ báyìì:

1. Àfidípò

2. Àfiwé tààrà

3. Àfiwé e̩lé̩lò̩ó̩

4. Ìfohunpèèyàn


5. Àwítúnwí

6. Àsọrégèé

7. Àjùmò̩rìn ò̩rò̩

8. Ìfìrómò̩rísí

9. Ìfò̩rò̩dárà

10. Ìwó̩hùn