Àkọtọ́ Èdè Yorùbá
Àkọtọ́ ni ètò tí a máa ń tẹ̀lé láti kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ nínú èdè. Ní èdè Yorùbá, ábídí tí a máa ń lò ni lẹ́tà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, àwọn ni a, b, d, e, ẹ, f, g, gb, h, i, j, k, l, m, n, o, ọ, p, r, s, ṣ, t, u, w, y.
Ìró àti lẹ́tà
àtúnṣeÀwọn ìró ni a máa ń tò pọ̀ láti di ọ̀rọ̀. Àwọn ìró tí lẹ́tà dúró fún ni kọ́ńsónáǹtì, fáwẹ̀lì àìránmúpè, àti fáwẹ̀lì àránmúpè.
Kọ́ńsónáǹtì
àtúnṣeKọ́ńsónáǹtì méjìdínlógún ni a ní lédè Yorùbá, tí a sì máa ń lo. Àwọn ni; b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y.
Fáwẹ̀lì àìránmúpè
àtúnṣeMéje ni fáwẹ̀lì àránmúpè. Àwọn lẹ́tà tí a sì máa ń lò fún wọn ni ; a, e, ẹ, i, o, ọ, u.
Fáwẹ̀lì àránmúpè
àtúnṣeFóníìmù fáwẹ̀lì àránmúpè mẹ́rin ni ó wà. Àwọn lẹ́tà tí a sì máa ń lò fún wọn ni; an, ẹn, in, ọn, un.
Ìpinnu ìjọba lórí àkọtọ́ ọdún 1974
àtúnṣeLẹ́yìn tí ìjọba Ìwọ̀-Oòrùn ti yan ìgbìmọ̀ kan ní 196 àti òmíràn ni 1969, ìjọba àpapọ̀ gba àwọn ìròyìn wọ̀nyí ní 1974, ó sì sọ wọ́n di ìlànà tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé nípa kíkọ èdè Yorùbá. Lára àwọn ìpinnu náà ni...
Yíyọ "í" nínú sípẹ́lì àwọn ọ̀rọ̀ kan
àtúnṣe- aiya - aya
- ẹiyẹ - ẹyẹ
- aiyé - ayé
- àìyà - àyà
- pẹ́pẹ́iyẹ - pẹ́pẹ́yẹ
Yíyọ ìṣùpọ̀ kọ́ńsónáǹtì kúrò nínú sípẹ́lì wa
àtúnṣeÌṣùpọ̀ kọ́ńsónáǹtì ni ìgbà tí kọ́ńsónáǹtì wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ nínú ọ̀rọ̀ kan. Ìyẹn ni pé kọ́ńsónáǹtì méjì ò gbọdọ̀ dúró tira nínú ọ̀rọ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ:
- Otta - Ọ̀tà
- Offa - Ọ̀fà
- Òshogbo - Òṣogbo
- Ògbómọ̀shọ́ - Ògbómọ̀sọ́