Àlọ́
Àlọ́ ni ẹ̀yà lítíréṣọ̀ Alohùn Yorùbá tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ó tàbí dá wọ́n lára yá. Ó jẹ́ àṣà ìkọ́mọ̀lẹ́kọ̀ó àti ìdárayá fún àwọn ọmọdé. Àlọ́ lè wáyé nípa sísọ ìtàn kúkúrú akọ́nilọ́gbọ́n tàbí kí ó jẹ́ ìbéèrè àdìtú.
Àkókò Ìpàlọ́
àtúnṣeAlẹ́, pàápàá jùlọ nígbà tí òṣùpá bá tàn ni àwọn àgbà àdúgbò máa ń kó àwọn ọmọdé jọ láti pàlọ́ fún wọn.
Ìwúlò Àlọ̀
àtúnṣeÀlọ́ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàtì tí àwọn Yorùbá ń gbà láti fojú àwọn ọmọ wọn mọlé sí ìwà, àṣà, ẹ̀sìn àti láti ṣàgbéga fún ìtẹ̀síwájú èdè wọn láti orí ìran kan sí òmíràn.
Oríṣi Àlọ́
àtúnṣeÀlọ́ pín sí oríṣi méjì, àkọ́kọ́ ni, Àlọ́ Àpamọ̀ èkejì ni Àlọ́ Àpagbè.[1]
Àlọ́ Àpamọ̀jẹ́ àlọ́ tí apàlọ́ yóò pa gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè fún àwọn agbálọ̀ọ́ láti yẹ ọpọlọ wọn wò bóyá wọ́n gbédè, mọ àṣà, mọ ìṣirò, lọ́gbọ́n àti lè ronú jinlẹ̀ sí èsì àlọ́ náà dára dára. Àlọ́ Àpagbè jẹ́ àlọ́ tí ó ma ń wáyé lẹ̀yìn àlọ́ àpamọ̀ tí ó sì kún fún ìtàn, orílẹ̀, ìlú, ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹ̀, tènìyàn tàbí tẹranko, tí ó sì ma ń ní orin àti ìlù nínú fún ẹ̀kọ́ àti ìdárayá fún gbogbo olùkópa.[2]
Ìgbésè Àlọ́
àtúnṣeLẹ́yìn tí àwọn ọmọdé bá ti kóra wọn jọ tí wọ́n sì pagbo, ẹnìkan yóò dúró gẹ́gẹ́ bí apàlọ́, ẹni yìí lè jẹ́ àgbàlagbà ọkùnrin tàbí obìnrin, bẹ́ẹ̀ ó sì lè jẹ́ ọmọdé lọ́kùnrin tàbí lobìnrin, tì àwọn tókù yóò sì jẹ́ agbálọ̀ọ́ tàbí ajálọ̀ọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àlọ́ àpamọ̀ ló kọ́kọ́ ma ń wáyé kí wọ́n tó pàlọ́ àpagbè. Apàlọ́ yóò ma sọ pé: Apàlọ́ : Ààlọ́ ooooooo? Àwọn Ajálọ̀ọ́: Ààlọ̀ọ̀ọ̀ọ̀ọ̀ọ̀! Apàlọ́: àlọ́ mi dá párá, ó kù fìrì, ó dá firi-gbágbòó! Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìfáàrà fún àlọ́ àpagbè. Lẹ́yìn tí apàlọ́ bá ti pàlọ́ rẹ̀ tán, yóò bèrè ẹ̀kọ́ tí olúkúlùkù rí kọ́,dìmú nínú àlọ́ náà.
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Oyelẹsẹ, J. O (2018-12-11). "Àlọ́ o. Apa kini, Àlọ́ apamọ - Catalog". UW-Madison Libraries. Retrieved 2018-12-11.
- ↑ "Àlọ́-àpamọ̀ (Yorùbá Riddles) Archives". Ìtàn Yorùbá, Ìròyìn Yorùbá, Ètò, Òwe ati Ìgbé-ayé Yorùbá (in Èdè Latini). Archived from the original on 2018-08-30. Retrieved 2018-12-11.