Àlọ́ Ìjàpá
Ìdí tí orí Ìjàpá fi pá
Apààlọ́ :Ààlọ́ o!
Ègbè Ààlọ́ :Ààlọ̀!
Apààlọ: Ààlọ́[1] mí dá gbà-á, ó dá gbò-ó, ó dá fìrìgbagbóò, o dálérí Ìjàpá tó lọ jí ẹ̀bẹ ní ilé àná rẹ̀.
Ní ìgbà láíláí, àbúrò ìyàwó Ìjàpá kan fẹ́ gbé ìyàwó. Àwọn òbí ọkọ ìyàwó ti fi lé potí, fọ̀nà rokà, pe onílé àti àlejò wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó aláririn náà.
Yáńníbo, ìyàwó Ìjàpá ti lọ sí ilé won nígbàtí ètò ìgbéyàwó náà ti ku bíi ọjọ́ méje láti lọ ṣe àmójútó, bẹ́ẹ̀ni Ìjàpá ọkọ rẹ̀ gbaruku tìí fún gbogbo ìnáwó tó máa na. Nígbàtí ọjọ́ ko, Ìjàpá náà yọjú si wọn ní ilé àná rẹ̀ láti bá wọn ìpalẹ̀mọ́: wọ́n t'ojoko wọn kọ́ àtíbàbà, wọ́n sètò onílù. Àwọn obìnrin ṣètò oúnjẹ lórísirísi: ẹ̀bẹ,ẹ̀wà, eran díndín, íyán gúngún,dòdò, àkàrà, iṣu àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Nígbà tí Ìjàpá ṣe tán, ó wẹ̀, wọ́n fún ní yàrá kan tí o kagùn sí ilé oúnjẹ pé kí ó sùn díè kó tó di alẹ́ tí ètò ìgbéyàwó máa bẹ̀rẹ̀. Oòrùn oúnjẹ títàsánsán inú yàrá yìí kò jẹ́ kí Ìjàpá ó lè sùn.Ẹ̀bẹ ni wọ́n ń sè lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ni òun gbàdúrà kíkankíkan kí wọ́n sọ̀ ó kalẹ̀ wọnú yàrá oúnjẹ lọ[2].
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá ìyàwó Ìjàpá ti bù ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ òṣíkí tí ó ni eran ìgbé ninu àti iyán wá fún Ìjàpá, ìyẹn kò tẹ́ ẹ lọ́run bíi ẹ̀bẹ tó pọ́n rẹ́dẹ́rẹ́dẹ́ pẹ̀lú epo lori. Lẹ́yìn tí Ìjàpá ti jẹun tó yó tan, ó sì ń gbèrò láti jẹ ẹ̀bẹ, kété tí wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sínú yàrá; Ìjàpá sọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́ṣẹ̀ ó ṣí fìlà rẹ̀ o bu ẹ̀bẹ síi. Ó sì dé mó orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ni ẹ̀bẹ gbígbóná ń jọ lórí. Ìjàpá yára lọ sí ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ pé òun fẹ́ lọ pàrọ̀ aṣọ nílé, aṣọ ìṣe ní òun wọ̀ tẹ́lẹ̀. Àna rẹ̀ fẹ́ sìn ín sọ́nà, Ìjàpá ní rárá kí wọ́n má ṣẹ̀ yọnu. Bí omi se ń yọ lójú ni ikùn ń yọ nimu,wọ́n bí pé kí ló de, ó ní o fẹ́ tẹ oun díè ni. Àná rẹ̀ ní kó lọ tọ́jú ara rẹ̀ nílé.
Nígbàtí yóò fi délé ooru ẹ̀bẹ gbígbóná ti bó ìwọ̀nba irun tó wà lórí rẹ̀, ẹ̀bẹ kò ṣe jẹ mọ́, irun ti kún inú oúnjẹ náà, orí ti bó fálafàla. Ìjàpá wo ogbẹ́ títí, ó san ṣùgbọ́n irun kò wù níbè mo. Lati ìgbà yẹn ni ori Ìjàpá ti pá.
Ìdì àlọ́ mi rẹ̀ gbáńgbáláláká,
Ìdí àlọ́ mi rẹ̀ gbáńgbáláláká,
Bí ń bá parọ́, k'ágogo enu mi kó má ró,
Bí ń ò bá paró, k'agogo enu mi kó ró lẹ́mẹ̀ẹta
Ó di pó .......pó ........pó!
Ẹ̀kọ́ Ààlọ́
àtúnṣeOjúkòkòrò kò dára, ohun tí wọ́n bá ti fún wa ni kó tẹ́ wa lorun.