Àpètúnpè
Nínú ìhun tí a ṣẹ̀dá láti ara mìíràn ni a ti máa ń rí àpètúnpè ṣùgbọ́n àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ kan wà nínú èyí tí àpètúnpè máa ń jẹ yọ, bóyá ń ṣe ni a ṣẹ̀dá wọn tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n a ó lè mọ orírun wọn mọ́. Bí àpẹẹrẹ - egungun, òkùnkùn, eṣinṣin, agogo. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àpètúnpè kíkún nínú ìrísí wọn. Oríṣi àpètúnpè méjì l'ó wà.
Àpètúnpè ẹlẹ́bẹ
àtúnṣeA máa ń rí àpètúnpè yìí nínú ìsọdorúkọ láti ara ọ̀rọ̀ ìṣe àti ìsọ-ọ̀rọ̀-ìṣe-dí-ọ̀rọ̀-àpèjúwe. Fún ìsọdorúkọ, a ṣe àpètúnpè fún kọ́ńsónáńtì àkókò, a sì fi fáwẹ́lì 'í' olóhùn òkè kún un. Bí àpẹẹrẹ
* lọ - lílọ
* rìn - rírìn
Fún ìsọ-ọ̀rọ̀-ìṣe-di-ọ̀rọ̀-àpèjúwe, a tẹ́lẹ̀ ìlànà kan náà àfi pè fáwẹ́lì 'u' lè gba ipò fáwẹ́lì 'i' nínú àwọn ọ̀rọ̀ àpèjúwe kan. Bí àpẹẹrẹ
* rùn - rírùn
* kúrú - kúkúrú
Àpètúnpè kíkún
àtúnṣeA máa wáyé nínú àwọn ìhun wọ̀nyí
A) Ìsọdorúkọ - nínú oríṣi ìsọdorúkọ mẹ́rin ni a ti ń rí àpètúnpè kíkún
* ọ̀rọ̀ orúkọ + ọ̀rọ̀ orúkọ: ará ọkọ = aróoko
* àpólà ọ̀rọ̀ ìṣe + àpólà ọ̀rọ̀ ìṣe: wolé = woléwolé
* ọ̀rọ̀ orúkọ + àfòmọ́ àárín + ọ̀rọ̀ orúkọ: oríṣi méjì ni èyí
- oní 'kí': ẹja kí ẹja = ẹjakẹ́ja
- òní 'ní': àgbà ní àgbà = àgbàlagbà
Àpètúnpè Ìsòrí Ọ̀rọ̀
àtúnṣeOríṣi méjì àpètúnpè yìí ni ó wà
Àpètúnpè tí kò ní ìyípadà ohùn: a ní oní ọ̀rọ̀ àpèjúwe, òǹkà abbl
àtúnṣe* burúkú - burúkú burúkú (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
* mẹ́ta - mẹ́ta mẹ́ta (òǹkà)
* kíá - kíákíá (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé)
Àpètúnpè oníyìípadà ohùn: ìsòrí ọ̀rọ̀ lè jẹ́ ọ̀rọ̀ àpèjúwe, ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tàbí ọ̀rọ̀ orúkọ
àtúnṣe* làǹtì - làǹtì lanti (ọ̀rọ̀ àpèjúwe)
* wúru - wúru wùru (ọ̀rọ̀ àpọ́nlé)
* fùkù - fùkùfúkù (ọ̀rọ̀ orúkọ)