Àpólà ọ̀rọ̀ orúkọ
Àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ nínú èdè Yorùbá ni, ọ̀rọ̀ orúkọ, àpapọ̀ ọ̀rọ̀ orúkọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ipò olùwà tàbí ipò àbọ̀, tàbí kẹ̀ àpapọ̀ ọ̀rọ̀ orúkọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀yán ni ipò olùwà tàbí ipò àbọ̀.
Yàtò si àwọn ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ ti a máa ń papọ̀ láti hun gbólóhùn Yorùbá, a tún máa ń lọ àwọn wúnrẹ̀n mìíràn láti hun gbólóhùn Yorùbá. Àwọn wúnrẹ̀n náà ni: àpólà-ọ̀rọ̀ àti awẹ́ gbólóhùn. Ọ̀kan nínú àwọn àpólà ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni a máa ń pè ni àpólà ọ̀rọ̀ orúkọ.
Nínú gbólóhùn èdè Yorùbá, iṣẹ́ tí àpólà ọ̀rọ̀ orúkọ, (ti a tún mọ̀ sí àpólà orúkọ), máa ń ṣe jọ èyi tí ọ̀rọ̀ orúkọ gan-an ń ṣe. Ohun ti a máa ń pè ni Ẹ jẹ́ ki a wo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí wò: 1. Bàbá Òjó ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́
Pẹ̀lú ìmọ̀ wá àtẹ̀yìnwá, tí a bá ní kí a ṣe itúpalẹ̀ gbólóhùn yìí sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, àlàyé ti a ó ṣe ní pe:
Bàbá - ọ̀rọ̀ orúkọ Òjó - ọ̀rọ̀ orúkọ (ẹ̀yán - ọ̀rọ̀) rà - ọ̀rọ̀ ìṣe ọkọ̀ - ọ̀rọ̀ orúkọ
ayọ́kẹ́lẹ́ - ọ̀rọ̀ orúkọ (ẹ̀yán ọ̀rọ̀)
Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àlàyé yìí jẹ́ òótọ́ síbẹ̀ ó ń fi í hàn bi ìmọ̀ wa nípa wúnrẹ̀n ti a lè fi hun gbólóhùn Yorùbá ti mo. Àlàyé mìíràn ti a lè ṣe, ti yóò si fi wá hàn bi ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ gbòòrò nínú gírámà Yorùbá ni pé:
Bàbá Òjó - àpólà orúkọ
Rà - ọ̀rọ̀ ìṣe
Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ - àpólà orúkọ
Àlàyé tún wà sì í ti a lè ṣe nípa bi ọ̀rọ̀ orúkọ méjèèjì ṣe jẹ́ sì ara wọn nínú gbólóhùn yìí, ṣùgbọ́n a ó máa bá irú àlàyé yìí pàdé nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí a ó kà níwájú.
2. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wá si ilé mi ni ọjọ́ ọdún
Yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ 'wá, si, àti ni' awọn wúnrẹ̀n yòókù jẹ́ àpólà orúkọ. Ẹ ṣe àkíyèsí pé àwọn wúnrẹ̀n ti a pè ni àpólà orúkọ ni gbólóhùn 1 àti 2 ti a fi ṣe àpẹẹrẹ wọ̀nyí ń ṣe iṣẹ́ olùwà àti iṣẹ́ àbọ̀, yálà àbọ̀ pékí/ àbọ̀ tààrà tàbí àbọ̀ ẹ̀bùrù; tàbí kẹ̀, iṣẹ́ àbọ̀ ọ̀rọ̀ - atọ́kùn bi àpẹẹrẹ gbólóhùn keji ti fihàn. Ẹ jẹ́ kí a tún yẹ àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ wò sì í.
Pẹ̀lú àlàyé ti a ṣe yìí a lérò pé a ti mọ ohun ti ń jẹ́ àpólà orúkọ àti àyè ti a ti lè bá wọn pàdé nínú gbólóhùn, èyí ni bóyá ni ipò olùwà, ipò àbọ̀ tààrà, ipò àbọ̀ ẹ̀bùrù tàbí ipò àbọ̀ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ atọ́kùn