Àròfọ̀ lórí àyíká
Àyíká ẹni niyì ẹni
àyíká tó jọjú
àyíká tó rẹwà
ni ibùgbé àlàáfíà
láì sí ìjà
láì sí ọ̀tẹ̀
láì sí ariwo
láì sí ogun
ọkàn ẹni a máa balẹ̀
l'áyìká tó lálàáfíà
òdòdó tó rẹwà
ṣe é gbìn sí àyíká
láti máa mú òórùn dídùn wá
igi gbíngbìn sáyíìká
le mún atẹ́gùn àlàáfíà wá sílé
ká mọ ògiri yílé po
lààbò lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi.