Àrùn tó máa ń ràn

Ọlọ́jẹ̀ jẹ́ kòkòrò kékeré tí a kò lè rí pẹ̀lú ojú lásán tó sì lè fa àìsàn tàbí àárẹ̀ sára èèyàn. A tún máa ń pè é ní kòkòrò tàbí arọ̀n kékeré nítorí ara olùgbàlejò rẹ̀ ló ti máa ń jẹun. Ọlọ́jẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ni fáírọ́ọ̀sì àti bakitéríà. Àwọn àìsàn tó má ń fà jẹ́ èyí tó le ran ni tó sì máa ń tàn ká, COVID-19 sì jé ọ̀kan lára irúfẹ́ àìsàn bẹ́ẹ̀.

Irúfẹ́ àwọn àrùn bẹ́ẹ̀

àtúnṣe

Èyí tí kò fara hàn àti èyí tó fara hàn

àtúnṣe

Wúnrẹ̀n “ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù” jẹ́ èyí tí a máa ń lò láti fi tóka sí ohunkóhun tó le fa àrùn tàbí àìsàn bó ti lè wù kó kéré mọ tí ó sì lè fara hàn bí a bá ṣáyẹ̀wò. Èyí sì máa ń dani lórí rú nítorí àwọn onímọ̀ ìṣègùn fi yé wa pé ó ṣe é ṣe kí a rí àwọn ohun tó máa ń fa àìsàn ṣùgbọ́n àìsàn ò ní sí níbẹ̀. A le pín àwọn ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù tó máa ń fàmì hàn sọ́nà méjì, àwọn sì ni èyí tó hàn gedegbe àti èyí tí àyèwò fínnífínní máa ń fi hàn. Àwọn ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù kan wà tó máa ń ṣiṣẹ́ tó sì máa ń ṣaápọn àmọ́ tí kò ní fàmì hàn rárá. Àwọn wọ̀nyí ni a mọ̀ sí subclinical, èyí ni pé kì í fara hàn. Látẹ̀ẹ̀ntì jẹ́ irúfẹ́ ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù mìíràn. Eléyìí kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́, ó kọ̀ máa lúgọ sápá kan ni. Àpẹẹrẹ ni latent tuberculosis. Fáírọ́ọ̀sì bìi herpes náà jẹ́ àpẹẹrẹ latent. A tún le pín ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù ṣóríṣiríṣi; àkọ́kọ́ ni èyí tí ó le tí ó sì burú tí ó sì máa ń fàmì hàn kíákíá.[1] Ẹlẹ́ẹ̀kejì ni èyí tó léwu tí àmì rẹ̀ sì máa ń fara hàn díẹ̀díẹ̀,[2] ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni èyí tí ó burú díẹ̀ tí àmì rẹ̀ sì máa ń pẹ́ kí ó tó fara hàn. Èyí tó gbẹ̀yìn ni èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ,[3] òhun sì ni ibi tí ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù náà ti bẹ̀rẹ̀ tí á sì ṣàn lọ gbogbo ara.

Ọ̀nà tó ń gbà ràn

àtúnṣe

Àrùn yìí máa ń ràn látara ẹnìkan sí ẹlòmíràn, oríṣi ọ̀nà sì ni ó máa ń gbà ràn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbọdọ̀ mọ̀ nípa àwọn ohun tó sodo sínu bo ́ṣe máa ń ràn láti le mọ bí a ṣe le dojú kọ ọ́. Àwọn ohun tó sodo sínu bo ́ṣe máa ń ràn ni:

(a) Aràn kékeré ni èyí tó máa ń fa ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù tó sì máa ń jẹun látara olùgbàlejò rẹ̀. Fáírọ́ọ̀sì ati bakitéríà ni èyí tó wọ́pọ̀ jùlọ. (b)Olùgbàlejò ni èèyàn tàbí ẹranko tó gbà á sára.

(d) Ọ̀nà àti jáde ni èyí tí aràn náà máa ń lò láti fi jáde lára olùgbàlejò rẹ̀.

(e) Ọ̀nà tí ó máa ń gbà láti ràn ni bí aràn náà ṣe máa ń kúrò láti ara ẹnìkan lọ sí ara ẹlòmìràn.

(ẹ) Agbègbè ni ibi tí aràn náà máa ń gbà tí ó bá kúrò lára ẹnìkan láti lọ sára ẹlòmíràn tó bá gbà à làyè.

(f) Ọ̀nà ìgbà wọlé ni ọ̀nà tó máa gbà wọ ara ẹlòmíràn.

(g) Olùgbàlejò ọjọ́ iwájú ni ẹni tó bá máa gbà á láyè láti wọlè.

Oríṣi ọ̀nà ni àwọn aràn yìí máa ń gbà ràn láti ara ẹnìkan wọ ara ẹlòmíràn. Ó le jẹ́ láti inú oúnjẹ, omi tàbí ìfarakanra, àwọn mìíràn sì máa ń wà nínú afẹ́fẹ́. Àwọn èyí tó wà nínú afẹ́fẹ́ ni a máa mẹ́nubà nínú àkọsílẹ̀ yìí.

Pàtàkì jùlọ àti Aláǹfààní

àtúnṣe

Pàtàkì jùlọ àti Aláǹfààní

àtúnṣe

Ó ṣe ni ní kàyéfì pé àrùn kéréje ni ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò yìí máa ń fà. Ewu tí àrùn máa ń fà dá lórí bí kòkòrò náà ṣe le fa ìjàm̀bá tó àti bí olùgbàlejò náà ṣe lè sá fun tó. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìlera pípé ara olùgbàlejò máa ń fa wàhálà fún kòkòrò tó bá wọlé láti fa àìsàn. Nítorí ìdí èyí ni àwọn onímọ̀ ètò ìlera ṣe pín àwọn kòkòrò búburú náà sí èyí tó Pàtàkì jùlọ àti èyí tó máa ń lo àǹfààní.

Àwọn kòkòrò tó pàtàkì jùlọ

àtúnṣe

Àwọn kòkòrò yìí ni èyí tó máa ń fa àìsàn látàrí gbígbé ara olùgbàlejò tó bá ní ìlera pípé láti fa àìsàn. Ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò yìí máa ń ran èèyàn nìkan àmọ́ àwọn àìsàn mìíràn le wáyé látàri àwọn kòkòrò mìíràn tó máa ń dá gbé tàbí èyí tó máa ń ran ẹranko àti ohun aláìlémìí.

Àwọn kòkòrò alàǹfààní

àtúnṣe

Àwọn wọ̀nyí ni èyí tó máa ń fa àìsàn tó máa ń ràn sára olùgbàlejò rẹ̀ tí kò ní ìlera tó péye tàbí èyí tó wọ ara èèyàn tó ṣiṣẹ́ abẹ. Àwọn kòkòrò yìí máa ń lo àǹfààní àìlera olùgbàlejò rẹ̀.

Ì̀nfẹ́ṣọ́ọ̀nù tó pàtàkì jùlo àti èyí tó ṣìkejì

àtúnṣe

Ì̀nfẹ́ṣọ́ọ̀nù tó Pàtàkì jùlọ ni èyí tó jẹ̀ gbòǹgbò àti ìdí àìsàn lágo ara. Ì̀nfẹ́ṣọ́ọ̀nù tó ṣìkejì sì ni àìsàn tó máa ń wáyé látàri ewu tí èyí tó pàtàkì jùlọ ti dá sílẹ̀.

Bó ṣe máa ń ràn

àtúnṣe

Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń pe àwọn àìsàn yìí ní àrànmọ́, ìdí abájọ ni pé ó rọrùn láti ràn sára ẹlọ̀míràn yálà nípa ìfọwọ́kàn tàbí ohun tó ń jáde lára wọn. Oríṣi àwọn àìsàn mìíràn tó ní ọ̀nà kan pàtó tó máa ń gbà ràn bí ọ̀nà ìbálòpọ̀ ò kì í ṣe àrànmọ́, kò sì nílò kí a sé aláìsàn mọ́lé. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àìsàn àrànmọ́ máa ń ràn láti inú afẹ́fẹ́, oúnjẹ tàbí omi tó ti gbàdòtí sára, ẹranko tàbí ìgbà tí kòkòrò bá gé èèyàn jẹ.[4]

Àwon àmì

àtúnṣe

Irúfẹ́ àmì tó máa fara hàn ní ṣe pẹ́lú irú àrùn tó wa ̀ní bẹ̀. Àwọn àmì mìíràn máa ń ran gbogbo ara bíi àárẹ̀, àìlèjẹun, ara rírù, ìbà, àágùn, òtútù àti ara ríro. Àwọn àmì kan sì máa ń hàn lápá kan bíi ara sísú tàbí rúdurùdu ní gbogbo ara, ikọ́ áti ikun nímú. Nígbà mìíràn, àmì ò kì í hàn lára àwọn ẹlọ̀míràn. Ì̀nfẹ́ṣọ́ọ̀nù ò kì í se nǹkan kan náà pẹ̀lú àwọn àrùn àrànmọ́, ìdí abájọ ni pé àwọn ìnfẹ́ṣọ́ọ̀nù mìíràn ò kì í fa àìsàn sára olùgbàlejó wọn.

Bakitéríà tabi fáírọ́ọ̀sì

àtúnṣe

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àmì kan náà ni àrùn bakitéríà àti fáírọ́ọ̀sì máa ń ṣàfihàn síbẹ̀ ó nira láti ṣe ìpínyà nínú èyí tó fa àrùn nínu méjèèjì. Mímọ ìyàtọ̀ nínú méjèèjì ṣe pàtàkì, antibìótíìkì ò le wo àrùn fáírọ́ọ̀sì sàn bẹ́ẹ̀ ó le wo àrùn bakitéríà sàn.


Ìtójú

àtúnṣe

Tí àrùn bá wọ àgọ ara èèyàn, àwọn oògùn tó máa ń dojúkọ àrùn ní a le lò láti dín agbára rẹ̀ kù. Oríṣi oògùn yìí ní ó sì wà. Antibìótíìkì le ṣiṣẹ́ fún bakitéríà àmọ́ kò le ṣiṣẹ́ fún fáírọ́ọ̀sì. Iṣẹ́ antibìótíìkì ni láti mú ìdínkù bá pípọ̀si bakitéríà tàbí láti pa á pátápátá.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Acute infections (MPKB)". mpkb.org. Retrieved 2019-12-09. 
  2. Boldogh, Istvan; Albrecht, Thomas; Porter, David D. (1996), Baron, Samuel, ed., "Persistent Viral Infections", Medical Microbiology (4th ed.), University of Texas Medical Branch at Galveston, ISBN 978-0-9631172-1-2, PMID 21413348, retrieved 2020-01-23 
  3. Foster, John (2018). Microbiology. New York: Norton. pp. 39. ISBN 978-0-393-60257-9. 
  4. (Higurea & Pietrangelo 2016)
  5. O'Brien, Deirdre J.; Gould, Ian M. (August 2013). "Maximizing the impact of antimicrobial stewardship". Current Opinion in Infectious Diseases 26 (4): 352–58. doi:10.1097/QCO.0b013e3283631046. PMID 23806898.