Àsà Ìgbéyàwó ní ilè Yorùbá

Ìgbéyàwó jẹ́ ìsopọ̀ láàrin ọkùnrin àti obìnrin láti di ọ̀kan ṣoṣo, láti jọ máà gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọkọ àti aya. [1] Àṣà ìgbéyàwó ní ilẹ̀ Yorùbá ṣe kókó, àwọn Baba ńlá wá bọ̀, wọ́n ní “ìyàwó dùn ún gbé, ọmọ dùn ún kó jáde”. Ìgbéyàwó jẹ́ àṣà tó ṣe pàtàkì ju ọmọ bíbí lọ pàápàá jù lọ láyé òde-òní.

Àṣà Ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá

Ẹni tí ó bá ti tó láti gbéyàwó, tí ó kọ̀ tí kò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn bàbá ńlá wa máa ń kí irú ẹni náà pé “awáyé má gbèyawó, kènkèkenke àtàrí bi erùu fila” won tún má n pe ni “ògòngò bi àgbà a tó baálé ilé má gbẹ́ ìyàwó. Oríṣiríṣi ònà ni a le gbà láti gbé iyawo ní èyí tí kò yo ònà tipátipá náà sílè. Yorùbá kì í fi ipá l’ówó, a kì í fi agbara bí omo, sùgbón wón a máa fi ipá gbé ìyàwó. Bí ó bà ti to àkókò fún olómokùnrin láti gbèyawó, tí Ó kò láti se be, àwon bàbáńlá wa má n ki eni naa pé “awáyé má gbèyawó, kènkèkenke àtàrí bi erùu fila” won tún má n pe ni “ògòngò bi àgbà a tó baálé ile má gbé ìyàwó.

Oríṣiríṣi Ìgbéyàwó

àtúnṣe

Ìgbèyawó Àsànte

àtúnṣe

Ìgbèyawó yi le waye nigbati ọkọ ìyàwó ba n fúra wí pé àwọn òbí ọmọbìrin náà fé fi ọ̀be ẹ̀yìn jẹ́ òun n’isu, tabi ti o ba rí I pé ojú ọmọbìrin naa ò gbé ibì kan. Irúfé ìgbéyàwó bayi maa n wáyé nígbàtí ọkọ-ìyàwó yi ba lo ji ìyàwó àfésónà re gbe yálà nìgbà tí ọmọbìrin naa ba n ti ona.

Ìgbèyawó Pàdémi nídìíkò

àtúnṣe

Èyí maa n wáyé nígbàtí àwọn olólùfé méjì bá ń fé ara wón sùgbón tí àwọn òbí wón mejeeji kò lówó si tabi ti won kò fe ki won fe ara wón. Báyìí ní àwọn ọkọ àti ìyàwó yóò bá sálo sí ìlú míiràn láti lo bèrè ìrìn àjò ayé wón láìsí ìyònda àwọn òbí wón níbè pé kí wón fé ara wón. Léyìn ọdún díè tí wón bá tí sálo , tí wón si tí bímọ méjì tàbí jù béè lo wón le pinnu àti padà wá si ìlú wón.

Ìgbèyawó Gbàmí- o- ràmí

àtúnṣe

Èyí ní irúfé Ìgbéyàwó tí ó sábà máà n wáyé láàrin onísègùn tàbí babaláwo àti ọmọbìrin. Èyí máà n selè nígbàtí ara ọmọbìrin náà kò bá ya, ti àìsàn tàbí egbò ńlá kan bá kolùú tí wón si ti náwó-nára sùgbón ti won o rójútu àìsàn náà, tí wón wà gbẹ̀ lo sí òdò babaláwo tàbí onísègùn kan, tí wón si se ìlérí fún onísègùn náà pé tí o bá le wo ọmọbìrin náà san, Òun ní ọmọbìrin náà yóò fe nìgbà tí ara re bá yá.

Ìgbèyawó Òrìsà

àtúnṣe

Àwọn àgbà bò wón ní wón ni babaláwo ní n s’oko àbíkú. Irúfé Ìgbéyàwó yi má ń wáyé nígbàtí wón bá wo àkosèjáyé ọmọbìrin ti ifá sí so fún wón pé òrìṣà funfun ní oko re. Àwọn òbí ọmọ yíì o wà lo gbẹ́ ọmọ náà fún àwọn ọlọ́bàtálá tàbí òdò babaláwo. Lónà kejì èwè, tí ọmọbìrin bá ti dàgbà tí okùnrin kankan lósì kọ̀ ẹnu ìfé si rárá. Tí wón bá lo ye ifá wo, babaláwo le so fún wón pé ọmọbìrin náà tí l’óko àti wípẹ́ òrìṣà kan ní oko re jẹ́.


TABI

Ìgbèyawó Ibile ati Ìgbèyawó

àtúnṣe

ÌGBÉSÌ ÀTI ÌLÀNÀ ÌGBÉYÀWÓ ABÍNIBÍ ILÈ YORÙBÁ

àtúnṣe

1. ÌFOJÚSÓDE : Ìfojúsòde máà ń wáyé nìgbà tí ebí kan bá n wà ìyàwó fún ọmọ wón okùnrin tí o tí bàlágà.[2]

2. ÌWÁDÍI : Àwọn Ẹbí ọmọkùrin ń rí ń yóò bẹ̀rẹ̀ síì se ìwádíi nípa ìdílé tí wón tí fé fé obìnrin, nítorí pé oríṣiríṣi ìdílé lo wà ìdílé míiràn àrùn búburú a máà yo wón lẹ́nu bi àpẹẹrẹ; àrùn ágànná, wárápá, àbísínwín abbl. Ìdílé míiràn àwọn obìnrin wón kii gbẹ́ ilé ọkọ dalé, ìdílé míiràn ìgbésì jíje a máà rò wón lórùn, ìdílé míiràn wón kii dàgbà, wón yóò tún te síwájú láti se ìwádíì irú ènìyàn tí Ọmọbìrin náà jẹ́ bóyá àsà ọmọ ní, bóyá òní kẹ̀bẹ̀kẹ̀bẹ̀ ní, léyìn èyí ní wón yóò wà lo bèèrè lọ̀wò ifá gẹ́gẹ́ bí Ẹlérì-ìpín tí kò lee puró, gbogbo àṣírí ọjọ́ ọ̀la ìgbéyàwó náà ní yóò han kẹdẹrẹ láti òdò ifá.

3. ALÁRINÀ : Alárinà jẹ́ okùnrin tàbí obìnrin tí o sùn mò ọmọbìrin, o le jẹ́ ọ̀ré tàbí mòlébí obìnrin òun ní eni tí o n ye ònà fún ọmọkùrin tí o fé fé ìyàwó kí àwọn mẹ́jèjì tó pàdé.

4. ÌSÍHÙN: Ìsíhùn ní gbígbọ́ àti gbígbà tí ọmọbìrin gbà láti jẹ́ kí ọmọkùrin náà jẹ́ àfésónà òun. Ọmọkùnrin yíì yóò wà san owó ìsíhùn fún àwọn ẹbí ọmọbìnrin yíì kí o tó le máà bá ọmọbìnrin náà sòrò, owó náà jẹ́ ọ̀ké kan láyé àtijówòn yóò sí fi obì àbàtà, ataare, àti orógbó sí owó ìsíhùn náà.

5. ÌTORO : Àwọn òbí àti díè nínú ẹbí Ọmọkùnrin yóò lo sí ilé òbí ọmọbìnrin láti so fún wón péà wón nìfé sí ọmọ wón obìnrin láti fé. Àwọn òbí ọmọbìnrin yíì yóò dájọ́ fún àwọn ẹbí Ọmọkùnrin pé kí wón padà wá , o le jẹ́ léyìn ọjọ́ mejé tàbí jù béè lo, àwọn ẹbí ọmọbìnrin yíì náà yóò lo se ìwádíi nípa irú ìdílé tí Ọmọkùnrin náà tí jáde, irú ènìyàn tí òun fúnra re jẹ́, wón yóò te síwájú láti se ìwádíi lọ́wọ́ ifá bí ọjọ́ iwájú ìgbéyàwó náà yoo se rí, tí ìwádíi wón bá yorí siré, gbígbọ́ àti gbígbà tí àwọn òbí ọmọbìnrin gbà láti fi ọmọ won obìnrin yíì gẹ́gẹ́ bí aya ní àwọn Yorùbá ń pé ní ÌJỌ́HEN tàbí bàbá gbọ́ ìyá gbọ́.

6. ÌDÁNA : Ìdána jẹ́ fífẹ́ obìnrin nísu lọ́kà, kíkó àwọn ẹrú ìdána lo sí ilé òbí obìnrin gẹ́gẹ́ bí àsà Yorùbá, àwọn ǹkan ìdána bíì: isu,obì, orógbó,àádùn, ataare,ìrèké, iyò, epo, oyin,ẹja-ọsàn, àti owó-orí ìyàwó.

7. Ayẹyẹ-Ìgbéyàwó: Ọjọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó jẹ ọjọ́ iyì àti ẹ̀yẹ fún ìyàwó,ọkọ-ìyàwó àti àwọn ẹbí wón. Ní ìròlé ọjọ́ tí ìyàwó yóò re ilé ọkọ re , léyìn tí ó bá tí múra tán, yóò lo dágbẹ́re fún àwọn òbí re àti àwọn ẹbí, àkókó yíì ní ìyàwó yóò máà sun ẹkún ìyàwó láti fi dágbẹ́re , láti fi dúpẹ́ àti láti fi gbà ìre/àdúrà lẹ́nu àwọn òbí àti ẹbí re, àwọn ọ̀ré re yóò si máà tẹ̀le e bí o tí n sùn ẹkún–ìyàwó kiri wón yóò máà re e lẹ́kún. Àṣálẹ́ ní yóò tó darí padà si òdò àwọn òbí re, léyìn ìwúre bàbá yóò fà ìyàwó lẹ́ ọwọ́ obìnrin tí o jẹ́ àgbà nínú awon ebi ọkọ lọ́wọ́, àwọn ìyàwó-ilé àti àwọn ọ̀ré ìyàwó yóò fi ìlù àti orin tẹ̀lẹ́ e lo sí ilé ọkọ re.

Ọkọ ìyàwó tí gbọdọ̀ kúrò ní ilé kí wón tó mú ìyàwó re dé, èèwò ní ni ilè Yorùbá ìyàwó kò gbọdọ̀ bá ọkọ re nílé ní alẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó wón, léyìn tí wón bá tí mú ìyàwó wolé tán ní ọkọ ìyàwó yóò tó wolé wa. Àwọn Ìyàálé ìyàwó yoo bu omi tutu si ese ìyàwó tuntun lenu ona abawole, ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nípa èyí ní wípẹ́ kí ìyàwó le fie se ẹ̀rò wolé ọkọ re.

Léyìn èyí wón yóò dojú igbá gbígbẹ délè kí ìyàwó tuntun fie se fo o, àwọn Yorùbá ní ìgbàgbọ́ pé iye ònà tí igbá yíì fo sí ní iye ọmọ tí ìyàwó yóò bí, tí o bá wuu o le má bí to béè tàbí kí ó bí jù béè lo.

8. ÌBÁLÉ: Ọkọ-ìyàwó àti ìyàwó re yóò jo ní ìbálòpọ̀ fún ìgbà àkókó ní alé ọjọ́ ìgbéyàwó wón láti mò bóyá ìyàwó tuntun yíì ko I tii mò okùnrin rí. Àwọn ọ̀bí ọkọ yóò tité aso funfun sí ori ìbùsùn nínú yàrá ọkọ ìyàwó láti fi gbà ìbálé ìyàwó re. Iyì ńlá ní fún àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ re bá nílé, ó túmò sí wípẹ́ ọmọbìnrin náà kò tii mò okùnrin rí. Odidi àgbè ẹmu tàbí odidi paali ìsáná,iyán àti ọbè tí o dára ní àwọn ẹbí ọkọ-ìyàwó yóò gbẹ́ lo fún àwọn òbí iyawo laaro kùtù ọjọ́ kejì láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ wón wípẹ́ odidi ní wón bá ọmọ wón , èyí ní óúnje ìbálé, ìyàwó yóò tún gbà owó ìbálé tii se ọ̀ké-méjì lọ́wọ́ ọkọ re. Ìtìjú àti àbùkù ní fún ìyàwó ti ọkọ re kò b ànílè, ìlàjì agbè ẹmu tàbí ìlàjì paali ìsáná ní àwọn òbí ọkọ ìyàwó yóò fi ránsẹ́ sí àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ re kò b ànílè láti le jẹ́ kí wón mò wípẹ́ ọmọ wón tí mò okùnrin rí.

9. ÌKỌ́RÙN: Ọjọ́ karùn-ún tí ìyàwó wolé ọkọ re ní yóò tó jáde síta, láti se isé-ilé àkókó àti láti lo kí àwọn ẹbí ọkọ re. Ojo yíì náà ní yóò jẹ́ ìgbà àkókó tí yóò dáná ọúnje fún ọkọ re.

Àwọn Ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Traditional Marriage System In Yoruba Culture, Nigeria". Information Parlour. 2015-05-20. Retrieved 2020-04-04. 
  2. Efagene, Oke (2014-10-02). "Traditional Marriage Rites How It's Done In Yoruba Land". Pulse.ng. Archived from the original on 2020-02-14. Retrieved 2020-04-04.