Àtìláńtíìkì
Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi ara hàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, ní ẹ̀bá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fọ́nká láti ẹnu odò Senegal títí dé orílẹ̀ èdè Liberia. Díẹ̀ lára àwọn èdè tí ó pẹ̀ka sí abẹ́ orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí:
Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba