Àtòjọ àwọn òrìṣà Yorùbá

Àwọn wọ̀nyí ni àwòn Òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá.

Òrìṣà tó ga jù

àtúnṣe

Ọlọ́run Elédùmarè ní orúkọ mẹ́ta tí Yorùbá má ń pèé, àwọn ni:

  • Elédùmarè - Olùṣèdá ohun gbogbo.
  • Ọlọ́run - Olù kápá ọ̀run.
  • Ọlọ́fin - Olù sààmì láàrín ọ̀run àti  Ayé

[1]

Àwọn òrìṣà tó níiṣe pẹ̀lú ìpín

àtúnṣe
  • Ọ̀rúnmìlà -  Ó jẹ́ òrìṣà ọlọ́gbọ́n, ìpín, àti arínú róde.
  • Orí - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó rọ̀ mọ́ ìṣèdá tàbí ìpín

 Àwọn Òrìṣà Imọlẹ̀ tí ó jẹ́ akọ

àtúnṣe

  • Ọbalú Ayé - Ó jẹ́ òrìṣ̀à tí ó rọ̀ mọ́ àjàkálẹ̀ àrùn tí ó sì tún ma ń ṣe ìwòsan àjàkálẹ̀ àrùn.
  • Erinlẹ̀ - Ó jẹ́ òrìṣà ìwòsàn, ó sì tún ma ń ṣe ìwòsàn àrùn. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó ma ń mú ìtura bá ènìyàn
  • Èṣ̣ù - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ń gbé oríta, ó jẹ́ òrìṣà ẹlẹ̀tàn, tí ó sì ma ń ṣeni ní jàmbá
  • Ìbejì - Ó jẹ́ òrìṣà àwọn ọmọ méjì  tí a bí papọ̀, ó ma ń fúni lọ́mọ.
  • Kokou - Ó jẹ́ òrìṣà oní jàgídí-jàgan
  • Ọbàtálá - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó mọ orí àti gbogbo ara tó kù fún ọmó ènìyàn. Ó jẹ́ òrìṣà ìmọ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ òrìṣà tí ó mọ́ kangá tí ó sì ma ń ṣe déédé
  • Odùduwà - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ṣẹ àwọn ọmọ Yorùbá kalẹ̀ sí ilé Ifẹ̀
  • Ògún - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó rọ̀ mọ́ irin tàbí àgbẹ̀dẹ. Ó sì tún jẹ́ jagun jagun nígbà ayé rẹ̀
  • Òrìṣà Oko - Ó jẹ́ òrìṣà tí Yorùbá ma ń lò láti fi ṣètò ohun ọ̀gbìn
  • Ọ̀sanyìn - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ma ń ṣòfófó fúni. ó lè gbé inú ilé tàbí inú oko
  • Òṣùmàrè - Ó jẹ́ òrìṣà tó dàbí ejò tí ó ma ń ta àwọn àwọ̀ oríṣi méje sí ojú ọ̀run
  • Ọ̀ṣọ́ọ̀sì - Ó jẹ́ òrìṣà tí  wọ́n fi ń dẹ ọdẹ tàbí ro oko
  • Ṣàngó, Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ma ń sán àrá látojú ọ̀run

 Àwọn Òrìṣà Yorùbá tí ó jẹ́ abo

àtúnṣe
  • ́Àjà - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ń gbé inú igbó tàbí aginjù, kò yàtọ̀ sí iwin, ó sì ma ń ṣe ìwòsàn.
  • Ajé Olókun - Ó jẹ́ òrìṣà omi tí ó ma ń ṣ̀àánú ènìyàn pẹ̀lú ọrọ̀.
  • Ẹ̀fúùfù - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó níkàpá lórí ìjì tàbí atẹ́gùn.
  • Mawu - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó níkàpá lórí Òòrùn àti Òṣup̀á.
  • Ọ̀bà - Òrìṣà yí jẹ́ ìyàwó Ṣ̀àngó àkọ́kọ́ tí ó di omi
  • Olókun - Ó jẹ́ òrìṣà omi.
  • Ọ̀ṣun - Òrìṣà  yí jẹ́ òrìṣà omi, tí o ́ní ṣe pẹ̀lú ìfé, ẹwà, àti owó.
  • Ọya - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ní agbára láti dá ìjì, mọ̀nàmọ́ná, fífúni lówó, àti idán fún ọmọ́ ènìyàn
  • Yemọja - Ó jẹ́ òrìṣà olú-odò tí ó ní agbára púpọ̀.

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Awon asa ati orisa ile Yoruba in SearchWorks catalog". SearchWorks catalog. 2019-06-15. Retrieved 2019-07-02.