Àwọn Òkè Mandara
Mandara Mountains a(èdè Yoruba: Àwọn òkè Mandara) jẹ́ àwọn òkè tí ó wà ní àríwá àlà láàrin Cameroon àti Nàìjíríà, tí ó gùn láti Odò Benue ní (9°18′N 12°48′E / 9.3°N 12.8°E) dé àríwá ìwọ̀ oòrùn Maroua ní àríwá (11°00′N 13°54′E / 11.0°N 13.9°E).[1] Òkè tí ó ga jù níbẹ̀ ni Mount Oupay.[1]
Àdúgbò náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùgbé, pàápàá jùlọ, àwọn tí ó ń sọ èdè Chadi, pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Mofu àti Kirdi.[1][2]
Àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibè
àtúnṣeÀwọn òkè Mandara jẹ́ ibi tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùgbé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ibẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè àti ilẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, òkè náà jẹ́ ibi àbò fún àwọn tí ó ń sá fún àwọn akónilẹ́rú àti ogun.[3]
Àwọn ènìyàn ibẹ̀ ti wá ọ̀nà láti gbìn ọ̀gbìn bí ó tilẹ̀ pé ilẹ̀ òkè ni ibẹ̀.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Scheffel, Richard L., ed (1980). Natural Wonders of the World. United States of America: Reader's Digest Association, Inc. pp. 226–227. ISBN 0-89577-087-3.
- ↑ "A Dormant Volcanic Range in Adamawa". Folio Nigeria. Retrieved 17 August 2020.
- ↑ Riddell, James C., and David J. Campbell. “Agricultural Intensification and Rural Development: The Mandara Mountains of North Cameroon.” African Studies Review, vol. 29, no. 3, 1986, pp. 89–106. JSTOR, www.jstor.org/stable/524085. Accessed 7 Aug. 2021.