Àwọn èdè Austronésíà

Ẹbí àwọn èdè kan nìyí tí èdè tí ó wà nínú rẹ̀ tó ọgọ́fà. Àwọn tí ó ń sọ àwọn èdè yìí tó àádọ́rin lé ní igba mílíọ̀nù (270 million). Wọ́n ń sọ wọ́n láti Madagascar dé Eastern Island: Wọ́n tún ń sọ wọ́n láti Taiwan dé hawal títí dé New Zealand. Wọ́n tún máa ń pe Austronesian yìí ní Malayo-Polynesian. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹbí èdè tí ó tóbi jù. Ohun tí kò jẹ́ kí àwọn onímọ̀ mọ̀ dájú sáká iye èdè tí ó wà nínú ẹbí yìí ni pé ọ̀pò ìgbà ni wọn kì í lè dá èdè mọ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀ka-èdè. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn èdè yìí ti ń wọ inú ara. Ìyẹn ni pé ẹnì kan lè máa so èdè A àti B papọ̀ nítorí òwò tí ó ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn pàdé ara wọn. Ìpín mẹ́ta pàtàkì ni a máa ń sábì pín ẹbí yìí sí. Àwọn ìpín mẹ́ta náàs ni Western Austronesian, Eastern Austronesian àti Central Austronesian. Àwọn ẹgbẹ́ èdè tí ó wà nínú Western Austronesian tó ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta. Wọ́n ń bọ wọ́n ní Madagascar, Malaysia, àwọn Erékùsù Indonesia, Phillipines, Taiwan àti apá kan Vietnam àti Cambodia àti igun ìwọ̀-oòrùn New Guinea. Ara wọn máà ni àwọn èdè méjì Micronesia (tí wọ́n ń fẹ́ chamorro àti Palauan). Àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ Eastern Austronesian náà tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta èdè. Wọ́n tún máa ń pe ẹgbẹ́ Eastern Austronesian ní oceanic. Wọ́n ń sọ wọ́n ní New Guinea, gbogbo àwọn erékùsù bí ẹgbẹ̀rún méwàá ní Melanesia, Micronesia àti Polynesia ṣùgbọ́n àwọn tí ó ń sọ wọ́n kò ju mílíọ̀nù méjì àbọ̀ lọ (2.5million). Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹgbẹ́ Central Austronesian jẹ́ àádọ́jọ (150). Àwọn tí ó ń sọ wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rin àbọ̀ ní ààrin gbùngbùn àwọn erékùsù Indonesia.

Àwọn èdè Austronesian
Ìpínká
ìyaoríilẹ̀:
Maritime Southeast Asia, Oceania, Madagascar, Taiwan
Ìyàsọ́tọ̀:one of the world's major language families; although links with other families have been proposed, none of these has received mainstream acceptance
Àwọn ìpín-abẹ́:
Formosan (several primary branches)
Malayo-Polynesian (perhaps a sub-branch of Formosan)
ISO 639-2 and 639-5:map
[[File:

|350px]]