Àwọn ènìyàn Gbagyi

Gbagyi or Gbárí (plural - Agbagyi) jẹ́ orúkọ àti èdè àwọn ẹ̀yà Gbagyi/Gbárí tí wọ́n ni Olú Ìlú Àbújá tẹ́lẹ̀ tí Ààrin gbùngbùn Nàìjíríà, tí wọ́n tó Mílíọ́nù mẹ́jọ niye tí wọ́n ń sọ èdè náà. Gwari ni àwọn ẹ̀yà Hausa Fúlàní àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn ń pè wọ́n lásìkò ìkónilẹ́rú nílẹ̀ Nàìjíríà,. Ámọ́ àwọn ẹ̀yà yí nífẹ̀ẹ́ẹ̀ẹ́ sí kí wọ́n ma pe àwọn ní Gbagyi. Wọ́n ń gbé ní agbègbè Ìpínlẹ̀ Náíjà, Kàdúná, àti F.C.T Àbújá..A tún kè ṣalábàápàdé wọn ní Ìpínlẹ̀ bí Násáráwá àti Kogí . Àwọn Gagyi ni wọ́n jẹ́ ẹ̀yà tí ó pọ̀ jù lọ tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ìlú ní Middlebelt àti Ìlú Àbújá. Iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ wọn yàn láàyò ni iṣẹ́ agbẹ̀ àti àáró dídá.

Gbagyi people (Agbagyi)
Jarre-Gwari-Musée des Confluences.jpg
Regions with significant populations
Nigeria
Ẹ̀sìn

Christianity, Islam and Traditional African religion

Ìtàn wọn

àtúnṣe

Ètò ìṣèlú Àwùjọ won

àtúnṣe

Nínú ìtàn, àwọn Gbayi máa ṣàmúlṣàmúlò ọ̀nà ìbátan láti inú ẹbí bàbá bàbá wọn. Ibi tí àṣe Àárín ìlú parí sí ni ọ̀ọ̀dẹ̀ tí ó ń ṣàkóso agboolé kan láàrín ìlú wọn, èyí tí ẹni tí ó jẹ́ Dáódù àgbà jùlọ yóò ti máa láṣà lábẹ́lé. Ìpele àṣe tí ó ga julọ ni ti abẹ́ Ọba Esu , tí àwọn àgbààgbà olóyè lágbolé kòòkan náà sì ń ṣe ìrànwọ́ fun lórí àkósó ìjọba. [1]

Lóòtọ́ ni wípé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Gbagyi yàn láàyò, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú wọn sì tún ma ń ṣe ọdẹ , tí àwọn mìíràn sì yan ìṣ eniṣẹ́ ọnà láàyò pẹ̀lú, nípa mímọ ìkòkò, gbígbẹ́gi léte àti igbá fínfin láàyò gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òòjọ́. [2] Àwọn Gbagyi gẹ́ràn láti máa lo amọ̀ àti ìkòkò láti fi ṣọ̀ṣọ́ sí ara ilé wọn. Àwọn irinṣẹ́ àmúlò nínú ṣẹ́ omo dídá wọn ni Ọkọ́, àti Àdá, láti fi yẹ̀nà àti kọbè iṣu, Àgbàdo, Jéró, Ẹ̀pà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ibùdó wọn

àtúnṣe

Àwọn ẹ̀yà Gbagyi wà ní oríṣiríṣi ibùdó bí Middle Belt (Àárín gbùngbùn) ilẹ̀ Nàìjíríà. Wọ́n wà ní apá Ìwọ̀ Oòrùn Ilú Àbújá , agbègbè Ìlà Oòrùn Ìpínlẹ̀ Náíjà, agbègbè Ìjọba ìbílẹ̀ Chikun pẹ̀lú Olú-ìlú rẹ̀ ní Kújamá ni Ìpínlẹ̀ Kàdúná , Ìpínlé Násáráwá . [3] Àwọn ìlú Gbagyi ti ó ṣe pàtàkì jùlọ ni Minna, Kwakuti, Kwali, Wushapa (Ushafa), Bwaya (Bwari), Suleja, Diko ati Paiko. Díẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó mú kí àwọn ẹ̀yà yí ó fúnká ni ìjà àti ogun tí wón jà pẹ̀lú àwọn Fúlàní, nígvà tí àwọn Ònsọ̀tàn míràn sọ wípé títúká tí wọ́n túká dá lórí bí wọ́n ṣe ń wá ilẹ̀ tó lọ́ràá láti fi ṣe ọ̀gbìn.

Àwọn ìletò àwọn Gbágyi ma ń dá lórí ohun tí Won bá ń ṣe lọ́wọ́. Bí wọ́n bá ń dáko, wọn kìí jẹ́ kí ibùgbé wọn ó tobi nítorí kí wọ́n ba lè rí ilẹ̀ dá kò sí.

Bí wọn ṣe kúrò ní Ìlú Àbújá

àtúnṣe

Ẹ̀yà Gbagyi ni ó jẹ́ ẹ̀ẹ̀yà tí ó pọ̀jù lè láàrín àwọn ẹ̀yà tí wọ́n jọ ń gbé Ìlú Àbújá ṣáájú kí wọ́n yan ìletò náà gẹ́gẹ́ bí Olú Ìlú titun fún Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọdún 1991. Èyí ni ó ṣokùfà bí wọ́n ṣe fi orírun wọn sílẹ̀, pàá Pàá jùlọ Àpáta Zuma , [4] tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí Òòṣà ( deity) tí ó ń dá abo bo wọ́n nígbà ìṣòro. Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún wọn ní ilé, ilẹ̀ àti ohun tí wọ́n le fi ṣe dúkìá lẹ́yìn tí wọ́n gbalẹ̀ wọn lọ́wọ́ wọn. Ṣùgbọ́n, púpọ̀díẹ̀ lò gbé ibi tí ìjọba yàn dá fún wọn.

Àṣà wọn

àtúnṣe
 
Ikoko ti a fi ọwọ ṣe nipasẹ Ladi Kwali (YORYM-2004.1.919)

Awọn ènìyàn Gbagyi ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ aláfíà, olóòtọ́ àti ẹ̀yà tí ó koni mọ́ra jọjọ. Àwọn ará òkè Ọya ń tí wọ́ jẹ́ Hausa ń sábà ma ń sá báyìí elédè wọn wípé: " shi Gwari Gwari," tí ó túmọ̀ sí : “jẹ ki a ṣe bi Gbagyi” tàbí “;bíi Gbagyi”. Àwọn ènìyàn Gbagyi ma ń tètè faramọ́ gbogbo agbègbè tí wọ́nbá bá ara wọn.

Èdè wọn

àtúnṣe

Gbdè Gbagyi jẹ apakan ti ipin ipin Kwa tí ò ṣẹ̀ wáláti orílẹ̀ èdè Niger-Congo, [5] ẹ̀wẹ̀, àwọn onímọ̀ ìwádìí ìjìnlẹ̀ bii : Kay Williamson fi èdè náà sí abẹ́ Ìpín èdè Benue-Congo . [6] Àwọn ènìyàn Gbagyi ń sọ ẹ̀ka èdè méjì tí wọ́n sábà ma ń tọ́ka rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Gbárí (Gwari yamma) àti ẹ̀ka èdè Gbọnilẹ .

Ẹ̀sìn

àtúnṣe

Àwọn eniyan Gbagyi jẹ́ olùsìn ẹ̀sin Mùsùlùmí, Kírísítẹ́nì àti ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àbáláyé ti ilẹ̀ Adúláwọ̀. Wọ́n tún nígvàgbọ́ sí Òrìṣà kan tí wọ́n ń pè ní Shekwoi (ẹnìkan tí ó ti wà níbẹ̀ ṣáájú àwọn bàbá-ńlá wọn) [7] bákan náà ni wọ́b tún ń bọ òrìṣà bí Maigiro. [8] Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínù wọn tùn nígbàgbọ́ nínú àkúdàáyà.

Awọn itọkasi

àtúnṣe
  1. Shekwo, p. 25.
  2. Shekwo, p. 29.
  3. Rosendall, pp. 1.
  4. Shekwo, p. 39.
  5. Shekwo, p. 18.
  6. Rosendall, p. 6.
  7. Shekwo, p. 31.
  8. Shekwo, pp. 31.

Àwọn orísun

àtúnṣe
  • Shekwo, Joseph (1984). Understanding Gbagyi folktales : premises for targeting salient electronic mass media programs (Thesis). Northwestern University.
  • Rosendall, Elias (1998). Aspects of gbari grammar (Thesis). University of Texas at Arlington.