Àwọn ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ Yorùbá
Àwọn ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ Yorùbá
àtúnṣejẹ́ ònkà tí à fi ń ṣe ìṣirò iye ọjọ́, ọ̀sẹ̀, oṣù àti ọdún ní ilẹ̀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè tó kù lágbàáyé ti ní tiwọn náà.
- Ọjọ́ Àìkú. Jẹ́ ọjọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀ Yorùbá, nítorí wípé ó jẹ́ ọjọ́ Kíní nínú ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní ìbámu pẹ̀lú ònkà ọjọ́ ọ̀sẹ̀ Lárúbáwá bí ti ó wà nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu Yorùbá wípé ìrànwọ́ Yorùbá ṣẹ̀ wá láti ilẹ̀ Lárúbáwá.[1]
Ọjọ́ Aje
àtúnṣeỌjọ́ ajé ni ọ jọ́ tí a ma ń dájú iṣẹ́ ajé tí a sì ma ń mú iṣẹ́ owó pẹ̀lú ní ilẹ̀ Yorùbá, òun sì ni ọjọ́ kejì nínú ọ̀sẹ̀.[2]
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun
àtúnṣeÈyí ni ọjọ́ kẹta nínú ọjọ́ ọ̀sẹ̀ Yorùbá.
Ọjọ́ Ọjọ́rú
àtúnṣeÈyí náà ni ọjọ́ kẹrin tí àwọn ènìyàn ma ń sábà pe ní ọjọ́ Àlàrùba.
Ọjọ́ Ọjọ́bọ
àtúnṣeJẹ́ ọjọ́ tí ó ṣe ìkarún ún ní nínú àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ Yorùbá.
Ọjọ́ Ẹtì
àtúnṣeÈyí ni ọjọ́ kẹfà tí gbogbo ènìyàn ma ń pè ní ọjọ́ Jímọ̀.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta
àtúnṣeÈyí ni ọjọ́ tí ó kẹ́yìn nínú ọjọ́ ọ̀sẹ̀ Yorùbá.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "DAYS OF THE WEEK IN YORUBA". IleOduduwa.com the Source. 2017-10-10. Retrieved 2020-01-31.
- ↑ "ORÚKỌ ỌJỌ́: Days of the Week in Yoruba". The Yoruba Blog. 2018-12-30. Retrieved 2020-01-31.