Àyẹ̀wò àìsàn
Àyẹ̀wò àìsàn jẹ́ ìgbésẹ̀ tàbí ọ̀nà kan tí àwọn oníṣẹ́ ètò ìlera ma ń gbà láti fìdí òdodo àrùn tàbí àìsàn múlẹ̀ ní ara ènìyàn tàbí ẹranko kí wọ́n lè mọ irúfẹ́ oògùn tí wọn yóò lò si kí àláfíà aláàrẹ̀ náà ó lè padà sípò. Àwọn ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe àyẹ̀wò ni ìṣẹ̀lẹ̀ àtéyìnwá àti ìtan nípa ìlera aláàrẹ̀ àti àwọn ẹbí rẹ̀ lápapọ̀. Àyẹ̀wò ma ń dàmú àwọn oníṣẹ́ ìlera, nítorí àwọn àmì, ati àpẹẹrẹ ma ń yàtọ̀ síra wọn . Bí àpẹẹrẹ, pípòn apá kan nínú ara túmọ̀ sí oríṣiríṣi nkan, ṣùgbọ́n kò túmọ̀ sí ohun kan pàtó , ayàfi bí wọ́n bá ṣe ayẹ̀wò sí apá ibi tí ó pọ́n nínú ara yí kí wọ́n tó mọ̀ ohun pàtó kí wọ́n tó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. [1][2]
Àwọn ìgbésẹ̀ tí ó wà fún àyẹ̀wò
àtúnṣeÀwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì bí a bá fẹmẹ́ ṣe ìwádí àìsàn nípa àyẹ̀wò nìwọ̀nyí:
- Ṣíṣàkójọ pọ̀ àwọn ìtọ́ni lórí alámí tí ara bá ń funi. Wọ́n lè mọ̀ níoa ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí aláàrẹ́ pélú lílo ìlànà ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò lórí bí ìlera rẹ̀ ti ṣe ríátẹ̀yìn wá. Lílo ìlana àyẹ̀wò ojúkojú ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìṣèwádí níoa àìsàn lè fúni ní ìmòye nípa àìlera tí ṣẹlẹ̀ sí aláìsàn ní ọjọ́ iwájú.[3][4]
- Ìṣàkójọ-pọ̀ èsì àyẹ̀wò ma ń kẹ́sẹ-járí nígba tí àwọn oníṣẹ́ ìṣègùn ìlera bá pàmọ̀ pọ̀ ṣe ìwádí nípa àárẹ̀, àrùn tàbí àìsàn kan.[5]
Àwọn ọ̀nà tí a lè gba ṣe àyẹ̀wò àìsàn ni: Ṣíṣe àyẹ̀wò oríṣiríṣi pẹ̀lú lílo àwọn onírúurú irinṣẹ́ ìgbà-lódé. Ní pató, ìṣèwádí àìṣàn nípasẹ̀ àyẹ̀wò ní àwọn ìgbésẹ̀ ọlọ́kan ò jọ̀kan nínú.[6]
Àyẹ̀wò àrùn Covid-19
àtúnṣeWọ́n le ṣe àyẹ̀wò fún arùn Kòrónà pẹ̀lú lílo ìlana ìṣesí ati àpẹẹrẹ tí ó fi ń hànde, àmọ́ wọn kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ó wà nínú àgọ́ ara àyà fi tí wọ́n bá lo (rRT-PCR) tàbí CT tí ó níṣe pẹ̀lú àágùn ati awọn nkan mìíràn. Ìwádí kan ń lọ lọ́wọ́ nípa ìṣàfiwé láàrín PCR ati CT ní ìlú Wuhan , lórí àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà. Àbá tí wọ́n dá ni wípé CT tètè ma ń fi ìmọ̀sílára hàn ju PCR lọ. Lóòtọ́, CT kìí tètè fún wọn ní èsì pàtó. Ní inú oṣù kẹta ọdún 2020, iké-ẹ̀kọ́ ti Rediọ́lójì ti ó kalẹ̀ sí ilẹ̀ Amẹ́ríkà fọwọ́ si wípé wọn kò gbọdọ̀ lo CT fún àyẹ̀wọ̀ àkọ́kọ́ fún ìwádí nípa àrùn kòrónà.
Àyẹ̀wò fún fáírọ́ọ̀sì
àtúnṣeÀjọ ìlera agbáyé (WHO) fi ìlanà àti ìgbésẹ̀ tí àwọn oníṣẹ́ ìlera gbọ́dọ̀ tẹ̀lẹ́ láti fi ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ (RNA) fún àrùn COVID-19, ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Kíní ọdún 2020. Wọ́n ń lo ìlanà àtoríkòdì fún yẹ̀wò RNA tí ó jẹ́ ìwọ̀núbọ̀nú (rRT-PCR). Àyẹ̀wò yí lè ṣeé ṣe nínú ẹ̀jé tí wọ́n gbà sílẹ̀ àti àágùn, itọ́, ikun, ìtọ̀ tabí ìgbẹ́ tí ó bá jáde lára ènìyan. Tí èsì àyẹ̀wò yóò sì jáde láàrín wàkamàtí mélòó kan tàbi ọjọ́ péréte. Lápapọ̀, wọ́n tún ma ń ṣe àyẹ̀wò yí lórí aw9n kẹ̀lẹ̀bẹ̀ ọ̀nà ọ̀fun nítorí ìdíwọ́ tí ó ma ń mú bá èémí ní ọ̀fun. Ẹ̀wẹ̀, oúpọ̀ nínú awọn ilé-iṣẹ́ tí lórúkọ lágbàáyé ti ń gbé ìgbẹ́ṣe lórí bí wọn yóò ṣe ṣẹ̀dá agbo olómi kan tí yóò ma ṣèwádí nípa ìṣesí àwọn kòkòrò àtọ̀hún-rìn-wá àti awọn ọmọ ogun ara ígbà tí wọ́n bá kan ara wọn. Títí di ọjọ́ K3fà oṣù Keje ọdún 2020, wọn kò tíì rí ọ̀kan ṣe ní àseyọrí nínú awọn iṣẹ́ ìwádí yí tí ó lè ṣeé fi gbá àrùn Covid-19 wọlẹ̀ bámú bámú. Lára ìkan tí agbọ́ wípé ọ̀gbẹ́ni Cellex ṣe awárí rẹ̀ tí awọn ajọ oníṣẹ́ ìwàdí Serology fọwọ́ sí fún lílò ní àsìkò pàjá-wìrì ní orílẹ̀-èdè [[Amẹ́ríkà).[7]
Ìṣàyéwò nípasẹ̀ àwòrán yíyà
àtúnṣeÀwọn ìṣesí àwọn àwòrán tí ó níṣe pẹ̀lú érọ ayàwòrán ibi kọ́lọ́fín inú (CT) àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn kòróna. Àwọn àjọ ilẹ̀ itally tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí àwòrán ń gbíyanjú láti ṣe àkójọ gbogbo àwòrán àwọn tí wọ́n ti lùgbadì àrùn kòrónà ní orílẹ̀-èdè àgbáyé. Amọ́ ṣá, látàrí bí àwọn arùn náà ṣe ń gorí ara wọn lásìkò ìbúrẹ́kẹ́ àjàkákẹ̀ àrùn Covid-19 ati àrùn adenovirus, yíya àwòrán àwọn gbígba àwòrán àwọn tí wọ́n ti lùgbàdì àrùn pẹ̀lú PCR nira díẹ̀ nítorí ìwọ̀nú-bọ̀nú àwọn àrùn náà. [8] Wọ́n gbé iṣẹ́ ìwádí ńlá kan ní orílẹ̀-èdè China nípa ìyatọ̀ tí ó wà ní àrín lílo ẹ̀rọ ayawòrán CT ati PCR, tí wọ́n sì ṣàfihàn yíya àwòrán àwọn tí wọ́n ti lùgbàdì àìsàn kòróna kò ṣe pàtàkì. Wọ́n ń lo ìmọ̀ ìdàgbà-sókè ìmọ̀-ẹ̀rọ agbélẹ̀ rọ (AI) láti Artificial má fi ṣàwárí àwòrán àwọn 3ni tí wọ́n ti lùgbàdì àrùn yí nípa lílo àwọn ọ̀nà(CT).[9]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Crematogaster Lund, 1831". Integrated Taxonomic Information System. Retrieved 25 October 2014.
- ↑ CDC (2020-02-11). "Coronavirus Disease 2019 (COVID-19)". Centers for Disease Control and Prevention. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ Knipe, Henry (2020-06-15). "COVID-19 (summary) - Radiology Reference Article". Radiopaedia. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ "IgG Antibody Testing". Covid19. Archived from the original on 2020-07-12. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ "CT Provides Best Diagnosis for Novel Coronavirus (COVID-19)". Imaging Technology News. 2020-02-26. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ "Laboratory testing for 2019 novel coronavirus (2019-nCoV) in suspected human cases". WHO. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ Jannette Collins, MD; Eric J. Stern, MD (1998). "Ground glass opacity on CT scanning of the chest: What does it mean?" (PDF). Applied Radiology. Archived from the original (PDF) on 18 May 2012. Retrieved 1 February 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "CT provides best diagnosis for COVID-19 -- ScienceDaily". ScienceDaily. 2020-07-12. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ "Chest CT Findings in Coronavirus Disease-19 (COVID-19): Relationship to Duration of Infection". Radiology: 200463. February 2020. doi:10.1148/radiol.2020200463. PMID 32077789.