Èjè jé ìsàn(fluid) tí o má ún sàn káà kiri inú ara láti fún ara ní okun, oxygen àti àwon nkan míràn tó wúlò fún ara. Èjè kún fún orisirisi nkan tí ara nílò bi; homonu, okun, seeli funfun inú èjè, seeli pupa inú èjè àti be be lo. Pilasima(tí ódà bí omi) àti àwon seeli èjè bí seeli èjè funfun, seeli èjè pupa àti platelet ló parapò di èjè. Ìdásí aadorun ninú ogorun pilasima jé omi[1]. Hemoglobin ara seeli èjè pupa ló fún èjè ní àwò pupa rè[2]

, hemoglobin ara seeli èjè tún wa fún gigbe oxygen kaakirara. Seeli èjè funfun wà fún bíbà kòkòrò tó le fa aìsàn lara je, plateleti fún diídí ìsun èjè sita nigba tí ènìyàn bá sese. Èjè sàn ká kiri ara ninú àwon ohun èlò èjè tí a ún pè ní artiri ati veini, artiri ngbe èjè láti okàn ló sí ara, veini sì ún gbe èjè láti ara padà ló sí okan.

Àwon Ìtókasí

àtúnṣe
  1. "What Is Blood Made Of". Community Blood Center. Retrieved 2022-02-24. 
  2. Hewings-Martin, Yella (2017-06-30). "Why is blood red?". Medical and health information. Retrieved 2022-02-24.