Eto Oro Aje

Oro Aje

Ajibola, Olaniyi Olabode


AJIBOLA OLANIYI OLABODE

ÈTỌ̀ ORO AJÉ

Yorùbá tọ̀ wọ́n ní kí la ó jẹ làgba kí la ó ṣe, abálájọ tí ètò ajé fi mumú láyà gbobgo orílẹ̀ èdè àgbáyé tóó bẹ̀. Gbàrà tí ọ̀nà káràkátà oní-pà ṣí pààrọ̀ tayé ọjọ́ tun ti dotun ìgbàgbé ni ètò ajé ti dotun tó gbòòrò síwájú sí. Awọn ènìyàn wáá bẹ̀rẹ̀ síí ní lo àwọn ohun èlò bíi wúrà àti jàdákà láti máa fii se pàṣípààrọ̀ àwọn ohun tí wọ́n nílò. Eléyìí mú kí káràkátà láàrín-ín ìlú àti orílẹ̀ èdè tún gbináyá síi nígbà tí àwọn kù dìẹ̀ ku diẹ tí ń fa ìdílọ́wọ́ nínú káràkátà onípàṣípàrọ̀ ti kúrò ní bẹ̀. Tí abá kọ́kọ́ gbé ètò ayé ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú yẹ̀ wò fínní fínní, aórìí pe ohun erè oko ló jẹ́ lájorí ọrọ̀ ajé àwọn ènìyàn yìí. Àwọn erè oko wọ̀nyí ni wọ́n si ń fi ń ṣe pàṣípàrọ̀ láti tán àìní ara wọn ṣááju alábàápàbé wọn pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ funfun. Ṣíṣa lábàápàdé àwọn aláwọ̀ funfun yìí mú kí àwọn aláwọ̀ dúdú ní àǹfàní àti ṣàmúlò àwọn ohun èlò míràn bíi: Jígí ìwojú, Iyọ̀, ọti líle àti àwọn ohun míràn bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àti ibí yìí ni wọ́n ti kọ́ àṣà lílo àwọn ohun èlò táati dárúkọ ṣáájú yìí dípò pà sí pààrọ̀ tó mú ọ̀pọ̀ wàhálà lọ́ iwọ́. kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, ìlànà àti máa lo owó wá sí ojútáyé, tí ètò ọrọ̀ ajé sì wá búrẹ́kẹ́. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìbúrẹ́kẹ́ ọrọ̀ ajé yìí, ìyípadà díẹ̀ ló dé bá ipò ò ṣì tí àwọn aláwò dúdú yìí ti wà tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ́rí. Èyí tó pọ̀jù nínú èrè ọrọ̀ ayé ìgbà ló dé yìó lóńlọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun. Kàyéfì ńlá ló jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí tí ń pọ̀ sin i òṣì túbọ̀ ń bá àwọn aláwọ̀ dúdú fínra sí. Kàyéfì ọ̀rọ̀ yìí ò sẹ̀yìn ìwà imúni sìn adáni lóró tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí fimú àwọn gìrìpá tó yẹ kó fi gbogbo ọpọlọ àti agbára wọn ṣiṣẹ́ láti mú ayé ìrọ̀rùn wáá bá ilẹ̀ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. Nígbà tó yẹ kí àwọn gìrìpá aláwọ̀ dúdú máa ṣiṣẹ́ idàgbàsókè ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìlẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun ni wọ́n wà tí wọ́n ń bá àwọn ènìyàn yìí ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ńlo àwọn aláwọ̀ dúdú láti tún orílẹ̀ èdè ti wọn se, àti láti pilẹ̀ ọrọ̀ ajé tó lààmì láka. Gbogbo ìgbà tí ìmúni lẹ́rú yìí n lọ lọ́wọ́, tí ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí sì ń tẹ̀ síwájú, kò sí ẹyọ iṣẹ́ ìdàgbàsókè kan ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú. Ìgbà tí ìmúnilẹ́rú dáwọ́ dúró, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ti gòkè àgbà díẹ̀ ń se ni wọ́n tún yára gba ètò ìṣàkóso ìjọba lọ́wọ́ àwọn àláwọ̀ dúdú, tí wọ́n sì sọ pé, ọ̀làjú ni àwọn fẹ́ẹ́ fi wọ àwọn aláwọ̀ dúdú yìí tí ẹ̀wù ìdí nìyí tí àwọn fi tẹ wọ́n lóríba tí àwọn sì fi pá gba ijọba wọn. Òtítọ́ tó dájú nip é, àwọn aláwọ̀ funfun yìí ríi pé ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú dára fún àwọn iṣé ọ̀gbìn erè oko kan bíi: kòkó rọ́bà, ẹ̀pà, àti kọfí èyí tí ó wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ohun èlò àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ti dá sílẹ̀. Wọ́n wá fi tì pá tì kúùkù sọ̀ ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú di oko Ọ̀gbìn àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò tí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ti wọn. Ipò Ìṣẹ́ àti Ìmúni sìn yìí ni àwọn aláwọ̀ dúdú wà tí tí fi di ìgbà tí wọ́n sọ pé àwọn funfun wọn ní òmìnira. Ipò òṣì àti àre tí àwọn aláwọ̀ funfun fi àwọn ènìyàn yìí sí kò jẹ́ kí wọ́n ó lè dá dúró, kí wọ́n sì dáńgbájíá láti máage àwọn ohun ti wọ́n nílò ní ilé iṣẹ́ ìgbàlódé ti wọn fún raa wọn. Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ló sì wá ń dá iye owó tí ohun erè oko tó ń wá láti ilè àwọn aláwọ̀ dúdú yíò jẹ́, èyí ti ó ń túmọ̀ sí pé, ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni dídọ lọ́rọ̀ àti òdìkejì àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú wà. Ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé wà, tó bá sì ṣe wùn wọ́n ni wọ́n ń lò ó. Abálájọ tó fi jẹ́ owó tí wọ́n ń ná nílùú wọn fińṣe ìdíwọ̀n pàṣípàrọ̀ ọjà ní ọjà àgbàyé. Kódà, àwọn orílẹ̀ èdè kan tó ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ kan tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní, bíi epo rọ̀bì ò he è dá ohun kan ṣe lórí ohun àmúṣọrọ̀wọn yìí láì sí ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí níbẹ̀. Abálájọ tó fi ṣòro láti rí orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú kankan nínú àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà. Ọ̀wọ́ àwọn aláwọ̀ funfun ni agbára ètò ọrọ̀ ajẹ́ àgbéyé wà, àwọn ló sì ń pàṣe fún àwọn orílẹ̀ èdè tó kù ní pa ọnà tí wọn yíò gbà ṣe ìjọba àti ọ̀nà tí wọn yíò gbé ọrọ̀ ajé wọn gbà, tí wọ́n bá fẹ́ àjọ ṣepọ̀ dídán mọ́rán pẹ̀lú àwọn.