Isiro

Tábìlì ìsirò

Awoyemi, Jolaoluwa

AWÓYẸMÍ JỌLÁOLÚWA

ÌṢIRÒ

Àwọn Yorùbá ní ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe ìsirọ̀, bẹ́ẹ̀ ní àti ọmọkékeré ní àwọn Yorùbá ti ń kọ́ ọmọ wọn ni ìṣirò ní ṣíṣe. Wọn yóò ni kí ó máa fi ení, èjì kọrin, ṣere bíi

Ení bí ení ni ọmọde ńkawó

Èjì bí èjì ni àgbàlà ń tayò

Ẹ̀ta bi ẹta ẹ jẹ́ ka tárawa lọ́rẹ

Ayò tí ta náà tún jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Yorùbá fi máa ń kọ ìṣirò Yorùbá ni àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń ṣe ìsirò wọn fún àpẹẹrẹ “lé”, “dín”, “àádọ́”, “ẹ̀ẹ́dẹ́”, - jẹ́ àwọn ọ̀nà fún ìfilé àti ìyokúrò ìṣirò wọn.

Apẹẹrẹ ìṣirò Yorùbá

1 - óókan

10 - ẹ̀wá

20 - ogún

21 - Ọ̀kàn lè lógún (20+1 = ọ̀kan lé ni ogún)

26 - ẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n (30-4 = Ọgbọ̀n dín mẹ́rin)

30 - Ọgbọ̀n

40 - Ogójì (20x2 = Ogún méjì)

60 - Ọgọ́ta (20x3 ogún mẹ́ta)

100 - Ọgọ́rùn-ún (20x5) = Ogún lọ́nà márùn-ún)

120 - Ọgọ́fà (20x6 = Ogún lọ́nà mẹ́fà)

50 - àádọ́ta (20 x3 = 10, ẹ́wàá dín nínú ogún mẹ́ta)

200 - Igba

240 - Òjìlélúgba (40+200; Òjì = 40)

300 - Ọ̀ọ́dúnrún

340 - Ọ̀tàdín nírinwó (400-60 = ọ̀tà = 60 lọ́gbọ́ta)

800 - Ẹgbẹ̀rin (igba mẹrin 200x4)

900 - Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (1000-100 = Ọgọ́rùn-ún dín ni Ẹgbẹ̀rún

1000 - Ẹgbẹ̀rún

1600 - Ẹgbẹ̀jọ (200x8 = igba méjọ

2000 - Ẹgbẹ̀wàa (ẹgbàá) (200x10 – igba ní ọ̀nà mẹ́wàá)

4000 - Ẹgbàajì (2000x2)

6000 - Ẹgbàata (2000x3)

7000 - Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (8000-100 = Ọgọ́rùn-ún, dín nínú Ẹgbàárin (800)

10, 000 - Ẹgbàarùn-ún (Ẹgbẹ̀rùn-ún àádọ́ta ẹgbẹ̀rùn-ún - àádọ́ta ọ̀kẹ́).