Ìró Ohùn
Ìró ohùn ni lílọ sóke, lílọ sódo ohùn èniyàn nígbà tí a bá n sọ̀rọ̀. Ìgbóhùn sókè-sódò máa ń wáyé nínú ìpèdè Yorùbá. Ìdí niyí tí wọ́n fi pe edè Yorùbá ní èdè olóhùn. Ìró ohun mẹ́ta ni ó se pàtàkì ní èdè Yorùbá. À ń pè wónní iró ohùn geere. Iró ohun geere ni iró ohun tí ó dúró sí orí sílébu kan,tí kò ní ẹ̀tọ́ rárá. Àwon iró béè ni:
(i)Ìró ohùn òkè
(ii)ìró ohùn ìsàlè; àti
(iii) ìró ohùn àárín.
Àpèjúwe àwọn ohùn
àtúnṣeOhùn Òkè (/)
àtúnṣeÌró ohùn tí a gbé jáde nípa gbígbé ohùn sókè. Àpẹẹrẹ ni:
mímó (m:m)
jẹ́jẹ́ (m:m).
Ohùn Ìsàlẹ̀ (\)
àtúnṣeÌró ohùn tí a gbé jáde nígbà tí a gbé ohùn wá sí ìsàlẹ̀. Àpẹẹrẹ ni:
ìwà (d:d)
ọ̀kọ̀ (d:d).
Ohùn Àárín (-)
àtúnṣeÌró-ohùn tí a gbé jáde nígbà tí ohùn dúró ní agbede méjì ìró ohùn òkè àti ìró ohùn ìsàlẹ̀. A kì í fi àmì rẹ̀ sí orí fáwẹ̀lì. Àpẹẹrẹ ni:
rere (r:r)
ikin (r:r)
akin (r:r).
Àwọn òfin tó de ohùn
àtúnṣe- A kì í fi àmì ohùn sí orí iró kọ́nsónánti, àfi orí (m àti n) tí wọ́n jẹ́ kọ́nsónánti àránmú aṣesilébu. Apeere: Òronbó, gbangba, nǹkan, Abímbọ́lá, abbl.
- Kọ́ńsónánti kan náa ni o bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ìró fáwẹ̀lì àti ìró ohùn ọ̀tọ̀ ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀.
ÌLÒ OHÙN
Ní èdè Yorùbá, àmì ohùn máa ń ṣokùnfà ìyàtọ̀ ìtumọ̀. Bí àpeere: Bí ìró Ohùn ṣe fa ìyàtọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Èjì-ọ̀kán-yà:
bá - to meet - Òjó bá mi ní ọ̀nà.
ba - to hide - Òjó ba mọ́lẹ̀.
bà - to cover - Òjó ba sí etídò.