Ìwúre Fún Aláboyún
Ìwúre fún aláboyún ni àwọn ìwúre tí a máa ń wú fún obìnrin tó bá ní oyún. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé ipò ẹlẹgẹ́ ni ipò ìlóyún, torí náà sì ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú tó yàtọ̀ fún wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n mọ̀ pé oríṣiríṣi ibi ni ó lè máa wá sí ojú ọ̀nà wọn, ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń ṣe ìwúre fún aláboyún.
Ìwúre aláboyún
àtúnṣeẸsẹ̀ yóo tẹ́lẹ̀ láyọ̀ o,
A ó gbóhùn lyá;
A ó gbóhùn ọmọ;
Àsọ̀kalẹ̀ àlàáfià.
Ewé ki í bọ́ lára igi kó nigi lára,
Wẹ́rẹ́ ni a ó gbọ́ ó.
A kì gbẹ́bí ewúré,
A kì í gbẹ̀bí eku,
A kì í gbẹ̀bí ẹyẹ,
A kò ní gbẹ̀bí rẹ̀.
Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni à ń bá omi òkun,
Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni à ń bá omi ọ̀sà;
Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni a ó máa ba oyún náà;
Títí ọjọ́ yóò fi pé.
Àfọ̀n yóo gbó kí ó tó wọ̀
Bí àfọ̀n kò bá gbó kì í wọ̀,
Omi kò ní í pọ̀ ju omi,
Ẹ̀jẹ̀ kò ní í pọ̀ ju ẹ̀jẹ̀.
A ó gbọ́ ohùn ìyá,
A ó sì gbọ́ t'ọmọ.
Èdùmàre kò ní fi ọjọ́ ìkúnlẹ̀ dá ọ lẹ́jọ́,
Ewé abíwẹ́rẹ́ ni o ó jàá lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀.
Lágbárá àwọn iya tó sẹ̀ wá sílẹ̀,
Tiwa ò ni sòro ó o se.
Àṣẹ.