ÌWÚRE NÍBI ÌDÁNÁ ÌYÀWÓ
ÌWÚRE NÍBI ÌDÁNA ÌYÀWÓ
Kí Ọlọ́run kó fire kárí gbogbo wa.
Ogun tú ọkọ ká, tú aya ká,
Kó má mà ṣẹ̀ sórí wọn o.
Ọmọ tí ó wúlò, tí ó dára
Ni kí Olódùmarè fún wọn o.
Orógbó tí wọ́n gbé wá nìyí,
Obi rèé o,
Owó tí wón gbé wá náà rèé o,
Kí iyàwó, ọkọ, náà gba irú rẹ̀;
Lórí ọmọ tí wọ́n bá bí o.
Ọmọ wọn ọkùnrin náà,
Kí àwọn náà tún ṣe irú rẹ̀ lórí wọn.
Irú eléyií ni ká máa péjọ ṣe o,
Ká má péjọ ṣọ̀fọ̀ o.
Kí okó gbó,
Bórógbó ti í gbó.
Káya náà gbó,
Bórógbó ti í gbó.
Kí Ọlọ́run rán àánú sí wọn ò,
Kí ọkọ́ ọba àwọn èṣù,
Kó má kọ́ wọn lẹ́sẹ̀ o.
K'ọ́mọ inú wọn pọ̀,
Bíi tatare yií ṣe pọ̀.
Kí wọ́n má bí emèrè. Àṣẹ.