Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní Gúsù Sudan
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní Gúsù Sudan tí wọ́n tún ń dà pè ní COVID-19 ni ó gbòde kan ní orílẹ̀-èdè Sudan Gúúsù ọjọ́ Karùún oṣù Kẹrin ọdún 2020. Nígbà tí yóò fi di ọjọ́ Kẹsàán oṣù Keje, wọ́n ti rí àkọsílẹ̀ iye ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùún kan ó lé mọ́kandínlọ́gbọ̀n tí wọ́n ti lùgbàdì àìsàn yí, tí èèyan mọ́kànlélógójì ti dágbére-fáyé látàrí Ìbúrẹ́kẹ́ àjakálẹ̀ àrùn yí ní apá Gúsù orílẹ̀-èdèSudan.
Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní Gúsù Sudan | |
---|---|
Map of cases by state as of 8 May. Some cases are not shown if their location is unknown
0 cases or no data 1–9 cases 10–49 cases 50–99 cases | |
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | South Sudan |
Arrival date | Ọjọ́ Karùún oṣù Kẹrin ọdún 2020 (4 years, 7 months and 3 weeks) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 2,129[1] |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 1,065 (previously hospitalized)[1] |
Iye àwọn aláìsí | 41[1] |
Bí ó ṣe ń ṣẹlẹ̀ àti àkókò ìṣélẹ̀
àtúnṣe
Àwọn ìgbésẹ̀ lórí ìdènà àrùn COVID-19
àtúnṣeNí ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kejì ọdún 2020, ìjọba ilẹ̀ Gúsù Sudan fòpin sí ìgbòkègbodò ìrìnà ọkọ̀ òfurufú pàá pàá jùlọ sí orílẹ̀-èdè tí àrùn náà ti pọ̀ lápọ̀jù . [2] Nígbà tí ó di ogúnjọ́ oṣù Kẹta, wọ́n tún ti gbog o ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé fáfitì gbogbo pa títí di ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹ́rin. Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, ọ̀gbẹ́ni Hussein Abdelbagi pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ojúkò ìdárayá, òṣèlú, ati ilé ìjọsìn pátá pa fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà gbáko.[3] Lẹ́yìn 2yí ni wọ́n ṣòfin kónílé-ó-gbélé láti ọwọ́ agogo mẹ́jọ alẹ́ sí agogo mẹ́fà ìdájí ọjọ́ kejì.[4][5] Ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́ta ọdún 2020, wọ́n fi iye ènìyàn tí ó tó ọ̀rùndínlẹ́gbéta sí iyàrá àdágbé, tí púpọ̀ nínú wọn sì sá jáde lọ sí apá aríwá orílẹ̀-èdè náà, tí àwọn wọ̀nyẹn náà sì ti ẹnu ibodè wọn pa fún ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko.[6] Títí di ọjọ́ Karùún oṣù Kẹ́ta títí di ọjọ́ Karùún oṣù Kẹ́rin ọdún 2020, tí àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà ti tàn dé orílẹ̀-èdè Mali, orílẹ̀-èdè Gúsù Sudan nìkan ni kò tíì ní àkọsílẹ̀ kankan fún àrùn Kòrónà.
Ìgbésẹ̀ ti oṣù Kẹ́rin ọdún 2020
àtúnṣeNí ọjọ́ Karùún oṣù Kẹ́rin, wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà ní orílẹ̀-èdè náà láti ara ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n kan tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ ìṣọ̀kan agbáyétí ó darí wálé láti orílẹ̀-èdè Netherlands[4] Ethiopia.[7] Àkọsílẹ̀ yí ni ó sì mú kí orílẹ̀-èdè Gúsu Sudan ó jẹ́ orílẹ̀-èdè kọkànlélọ́gọ́ta ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti ó ti ní àkọsílẹ̀ àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà. Wọ́n fi aláàrẹ̀ náà sínú ilé àdágbé akàtà àjọ ìṣọ̀kan agbáyé, tí wọ́n sì ṣe ìwádí nípa iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti súnmọ́ aláàrẹ̀ náà.
Àkọsílẹ̀ èkejì ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹ́rin yí kan náà tí ẹni tó tún fara káṣá àrùn náà tún jẹ́ ìkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ìṣọ̀kan agbáyé tí ó jẹ́ obìnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta lọ tí òun náàbṣẹ́ríbwálé láti orílẹ̀-èdè Nairobi ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù Kẹ́ta tí ó sì fi ara rẹ̀ sínú ìyàrá àdágbé kí àrùn náà ó má ba tàn jù bẹ̀ẹ́ lọ. .[8] Àkọsílẹ̀ ẹnì kẹta ni obìnrin kan tí 9un náà tún jẹ́ ìkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé tí ó ti fara kín aláàárẹ̀ àkọ́kọ́.[9][10] Ìjọba orílẹ̀-èdè Gúsù Sudan fagilé lílọ-bíbọ̀ ọkò òfurufú lábẹ́lẹ́ ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹ́rin ọdún 2020. [11] Àkọsílẹ̀ aláìsàn karùún ati ìkẹfà ni ó wáyé ní ọjọ́ kẹtalélógú ati ọjọ́ karùnlélógún oṣù Kẹ́rin 9dún 2020, tí àwọn tí wọ́n lu gúdẹ àrùn yí jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Gúsù Sudan.[12] Lẹ́yìn tí wọ́n ti rí akọsílẹ̀ ènìyàn méjìdínlọ́gbọ̀n ní orílẹ̀-èdè yí, wọ́n ṣe àfikún òfin kónílé-ó-gbélé tí.ó ti bẹ̀rẹ̀ láti agogo mẹ́jọ alẹ́ sí agogo mẹ́fà ìdájí sí agogo méje alẹ́ sí agogo mẹ́fà àárọ̀ ojọ́ kejì. Tí wọ́n sì fi àyè gba àwọn ilé oúnjẹ kí wọ́n ma tajà wọn déédé, bákan náà ni wọ́n ti gbogbo ẹnu ìloro orílẹ̀-èdè náà pa pinpin. .[13] Orílẹ̀-èdè Gúsù Sudan ni iye ènìyàn tí ó ń gbé níbẹ̀ jẹ́ mílíọ́nù mẹ́rìndínlógún lápapọ̀.[4]
Oṣù Karùún ọdún 2020
àtúnṣeOrílẹ̀-èdè Gúsù Sudan bẹ̀rẹ̀ sí ṣí àwọn ọ̀nà èto ọtọ̀ ajé wọn gbogbo, wọ́n dẹ òfin kónílé-ó-gbélé lẹ́kẹ láti agogo mẹ́wàá alẹ́ sí agogo mẹ́fà ìdájí ọjọ́ kejì, àwọn kẹ̀kẹ́ alùpùpù wọn náà ń gbérò tí kò ju ẹyọ kan ṣoṣo lọ tí àwọn méjèjì sì gbọ́dọ̀ wọ ìbòjú, àwọn ọlọ́kọ̀ èrò náà ń gbé èrò méjì tí àwọn náà gbọ́dọ̀ wọn ìbòjú. Àwọn ilé-ìtajà gbogbo náà bẹ̀rẹ̀ òwò wọn ní pẹrẹu, àmọ́ wọn kò gbọdọ̀ pọ̀ ju márùún lọ ní ojúkò kan ṣoṣo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà ṣì wà nígboro síbẹ̀.[14] Wọ́n tún ṣí àwọn pápákò òfurufú gbogbo padà ní 9jọ́ Kejìlá oṣù Karùún, ọdún 2020 fún lílọ-bíbọ̀ lábẹ́lé àti kárí-ayé gbogbo.[15] Gbẹgẹdẹ gbiná ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Karùún ọdún 2020, Sudan ní akọsílẹ̀ ẹni akọ́kọ́ tó gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra látàrí àárẹ̀ àrùn COVID-19 tí ó ń jà ní orílẹ̀-èdè náà.[16] Nígbà tí yóò fi di ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Karùún kan náà, igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Gúsù Sudan ọ̀gbẹ́ni Riek Machar ati ìyàwó rẹ̀ Angelina Teny náà lu gúdẹ àrùn Kòrónà. [17] Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà fún ètò ìròyìn ìyẹn ọ̀gbẹ́ni Michael Makue Loweth ati gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe tí iye wọn jẹ́ mẹ́ẹ̀dógún tí Ààrẹ wọn yàn láti wagbò dẹ́kun sí àjakálẹ̀ àrùn Kòrónà ní orílẹ̀-èdè náà tún lùgbàdì àìsàn yí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Karùún yí náà. [18] Kò pẹ́ sí àsìkò yí tí igbákejì ààrẹ mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hussein Abdelbagi fara káṣá àrùn Kòrónà òun oẹ̀lú olóríìgbìmọ̀ àmúṣẹ́ṣe fún Ààrẹ ní 9jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Karùún ọdún 2020.[19] Vice President James Wani Igga announced he had tested positive on May 30.[20]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 "South Sudan: COVID-19 cases rise to 2,129 as 16 more detected". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-07-12. Retrieved 2020-07-12.
- ↑ "South Sudan halts flights to countries affected by coronavirus". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 16 March 2020. Retrieved 2020-04-05. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "South Sudan closes schools, universities amid coronavirus fears". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 21 March 2020. Retrieved 2020-04-05. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 4.0 4.1 4.2 Mayra Ajack, South Sudan 51st of 54 African nations to report virus case, Associated Press (5 April 2020).
- ↑ "South Sudan imposes nighttime curfew over coronavirus". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 26 March 2020. Retrieved 2020-04-05. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Northern Upper Nile under lockdown after citizens escaped from quarantine". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 28 March 2020. Retrieved 2020-04-05. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "South Sudan confirms first case of coronavirus". Reuters. 2020-04-05. https://www.reuters.com/article/healthcare-coronavirus-southsudan/south-sudan-confirms-first-case-of-coronavirus-idUKL8N2BT05N.
- ↑ "South Sudan confirms second case of coronavirus". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-04-09. Retrieved 2020-04-08.
- ↑ "South Sudan records third case of COVID-19". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-04-12. Retrieved 2020-04-09.
- ↑ "Education ministry to launch distance learning for students". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-04-17. Retrieved 2020-04-13.
- ↑ "South Sudan suspends interstate travels over COVID-19". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-04-18. Retrieved 2020-04-14.
- ↑ "South Sudan records its sixth coronavirus case". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-04-27. Retrieved 2020-04-26.
- ↑ "COVID-19: South Sudan reviews curfew as cases rise to 34". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-05-05. Retrieved 2020-04-29.
- ↑ "South Sudan loosens restrictions even as coronavirus cases increase". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-05-16. Retrieved 2020-05-08.
- ↑ "South Sudan reopens airports amid rise in COVID-19 cases". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-05-20. Retrieved 2020-05-13.
- ↑ "South Sudan records first COVID-19 death as cases rise". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-05-21. Retrieved 2020-05-14.
- ↑ "Dr. Riek Machar and wife test positive for COVID-19". Eye Radio (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-18. Retrieved 2020-05-18.
- ↑ "South Sudan Officials, COVID Task Force Test Positive for Virus". VOA. 19 May 2020. https://www.voanews.com/africa/south-sudan-focus/south-sudan-officials-covid-task-force-test-positive-virus.
- ↑ "South Sudan confirms 18 new COVID-19 cases". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-06-21. Retrieved 2020-06-15.
- ↑ "VP Igga tests positive for COVID-19". Radio Tamazuj (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-06-08. Retrieved 2020-05-30.