Ìfèdèṣeré
Ìfèdèṣeré jẹ́ ọ̀nà kan tí àwọn Yorùbá má ń gbà láti kọ́ ọmọdé lédè, kí ẹnu wọ́n ó le dá sáká níbi èdè pípé. Àwọn ọmọdé ka Ìfèdèṣeré yìí sí eré tí wọ́n sì má ń kó ara jọ láti ṣe eré náà nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á wo díẹ̀ nínú àwọn Ìfèdèṣeré tí àwọn ọmọdé sáábà má ń lò.
Ìfèdèṣeré- Ká múgbá lámù
àtúnṣeKá mú'gbá lámù ká fi dámù ó dení
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dèjì
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dẹ̀ta
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dẹ̀rin
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dàrún
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dẹ̀fà
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dèje
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dẹ̀jọ
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dẹ́sán
Ká mú'gbá lámù ká fi dámù ó dẹ́wá.
Ìfèdèṣeré tokínní tokéjì
àtúnṣeTokínní, tokéjì, toǹtorígí
ẹ̀wà làá jẹ sùn
Òyìnbó di kàtàkítí-ní-kandí pí
láá làá mi loolo - ẹ̀bá.