Ìfini ṣòwò nàbì (Sex Trafficking in Nigeria)
Ìkóniṣòwò nàbì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n fi ń kóni rìnrìn-àjò fini ṣòwò nàbì lọ́nà àìtọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìkóni ṣòwò nàbì yi tun jẹ́ ọ̀nà ìfini ṣè òwò ẹrú ìgbàlódé (TIP) ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fí fini ṣòwò nàbì lọ́nà àìtọ́ yí ma ń mú ìpálára àti aburú tó pọ̀ wà fún ẹni tí a mu ṣòwò yìí#, ẹbí rẹ̀ àti àwùjọ̀ rẹ̀ gbogbo. Ìkọ́ni rìnrìn-àjò lọ́nà àìtọ́ ma ń sábà dá lórí ìyanijẹ, ìrẹ́nijẹ, íṣẹrú àti ìfipá-múni ṣe ohun àìtọ́, pàá pàá jùlọ fífí àwọn ènìyàn tí wọ̀n bá kó rìnrìn àjò lọ́nà àìtọ́ náà ṣe òwò nàbì tí kò wá láti ọkàn wọn.
orílè-èdè | Nàìjíríà |
---|
Gẹ́gẹ́ bí òfin Trafficking Victims Protection Act of 2000 ṣe ṣe àpèjúwe rẹ̀, ni ó jẹ́ Ìgbanisíṣẹ́, ìgbanimọ́ra, ìpèsè fúnni, ìfipá múni, lọ́nà àti fífini ṣòwò nàbì lọ́nà àìtọ́ tí kò sí tọkàn ẹni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìbálòpọ̀ ipá tàbí ìfiniṣòwò nàbì pẹ̀lú awọ ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò tíì tó ọdún méjìdínlógún ni a lè pè ní íkóni rìnrìn-àjò lọ́nà àìtọ́.[1]
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ọmọdékùnrin àti áwọn ọmọdébìnrin ni wọ́n ma ń kó rìnrìn-àjò lọ́nà àìtọ́ ní kẹ̀tí-kẹ̀tì láti orílẹ̀-èdè wọn lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè bíi: Italy Saudi Arabia, North Africa, Europe, Faransé, Spain, Netherlands, Belgium, Austria, Norway,Amẹ́ríkà àti Asia fún òwò nàbì. Bákan náà ní wọ́n tùn ń ko àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin tó fi mọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ abilékọ rìnrìn-àjò lọ sí àwọn ìlú àti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìtòsí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Chad, Niger Republic, Benin Republic, Togo àti Ghana fún báárà ṣíṣe, òwò nàbì, iṣẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iye áwọn ènìyàn tí wọ́n ń kó rìnrìn-àjò kúrò lọ́nà àìtọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrín ọdún kan ma ǹ tó àádọ́talélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rin (750,000) níye, nígbà tí wọ́n ń kó ìdá tí ò lé ní àádọ́rin (75%) nínu wọn rìnrìn-àjò láàrì́n orílẹ̀-èdè náà, bákan náà ni ìdá mẹ́tàlélógún (23%) ni wọn ń ipinle kọọkan, nigba ti wọn n ko ida meji ninu wọn jade kuro ni orilẹ-ede Naijiria laarin ọdun kan.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Sex Trafficking - Sexual Violence - Violence Prevention - Injury Center". CDC (in Èdè Sípáníìṣì). 2018-04-12. Retrieved 2022-03-30.
- ↑ "Prevention of human trafficking". United Nations Office on Drugs and Crime. 2010-09-14. Archived from the original on 2022-04-15. Retrieved 2022-03-30.