Ìgbómìnà
Igbomina Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà jẹ́ ẹ̀yà èdè Yorùbá tí àwọn Ìgbómìnà ń sọ. Ní ilẹ̀ Yorùbá lóde òní, àwọn Ìgbómìnà wà ní ìpìnlẹ̀ Ọṣun àti Kwara.[1][2] Àwọn ìlú tí wọn tí ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣùn ní ìlá Ọ̀ràngún Òkè-Ìlá àti Ọ̀rà. Ní ìpínlẹ̀ Kwara, àwọn ìlú yìí pọ̀ jut i Ọ̀ṣun lọ. Ìjọba Ìbílẹ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn ti ń sọ Ìgbominà. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Ìfẹlodun, Ìrẹ́pọdun, Òkè-Ẹ̀rọ́ àti Isis. Ìlú tí wọ́n ti n sọ èka-èdè Igbómìnà ni ìjọba Ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódun ni Ìgbàjà, Òkèyá, Òkè-Ọdẹ, Babáńlá, Ṣàárẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní Ìjọba ìbílẹ̀ Irẹpọ̀dun, lára àwọn Ìlú tí wọ́n ti ń sọ ẹ̀kà-èdè Igbómìnà ni Àjàṣẹ́, Òró, Òmù-Àrán, Àrán-Ọ̀rin. Ní ìjọba ìbílẹ̀ Òkè-Ẹ̀rọ̀ ẹ̀wẹ̀, wọn a máa sọ Ìgbómìnà ni Ìdọ̀fin. Ní ti ìjọba Ìbílẹ̀ Isis, a rí ìlú bíì Òkè-Onigbin-in, Òwù-Isis, Èdìdi, Ìjárá, Ọwá kájọlà, Ìsánlú-Isis, Ọ̀là àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3]
Olúmuyiwa (1994:2) wòye pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀ka-èdè ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ní ẹ̀yà. Èyí náà rí bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà. Lóòótọ́, àwọn ìlú tí a dárúkọ bí ìlú tí a ti ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà máa ń gbọ́ ara wọn ni àgbọ́yé bí wọ́n ba ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀ oríṣiríṣI ni ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ láti ìlú kan sí èkejì. Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà Òrò sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ ni ẹkùn Òrò.
Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú Àpilẹ̀kọ Ẹ́meè A. F. Bámidélé.
- Ẹ̀KA ÈDÈ ÌGBÓMÌNÀ láti ọwọ́ A.F. Bamidele, UOA, Adó-Èkìtì, Nigeria
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
- ↑ "AFRICA - Igbomina people". 101 Last Tribes. Retrieved 2023-06-13.
- ↑ Dada, P.O.A. (1985). A Brief History of Igbomina (Igboona), Or, The People Called Igbomina/Igboona. Matanmi Press. https://books.google.com.ng/books?id=lqlRAQAAIAAJ. Retrieved 2023-06-13.
- ↑ "History of Igbomina – Igbomina Descendants Association UK". Igbomina Descendants Association UK. Retrieved 2023-06-13.