Ìgbaná
Ìgbaná tabi ìjóná ni a n pe gbogbo itunse apopoogun (chemical reaction) to n mu igbona ati imole wa. Igbana je ifesi Iresile-Isodioloksijini. Ni igba atijo won n pe gbogbo ifesi mo oksijini (O2) to mu igbona ati imole wa ni igbana. Sugbon loni a mo pe awon ohun alara miran na le fa orisi igbana. Iru awon ohun alara bayi ni Florini (F2) , Klorini (Cl2) at.bb.lo. Botiwukoje ni igba ti a ba n soro nipa igbana, lai se itumo mo ohun kankan, o tumo si igbana mo oksijini tabi afefe. Ni pataki awon igbana adapo alemin (organic compound) n sele pelu O2 tabi pelu awon ohun alara to ni oksijini bi afefe tabi baba oloksijini(II) (CuO).
Irú ìgbaná
àtúnṣeA le pin igbana si eyi topari ati eyi tikopari gege bi iye O2 to wa ati awon ìwàkání igba na.
- Igbana topari je igbana to n sele pelu opo oksijini ti ko ni adapo alegbogi (chemical compound) tikojona. O soro gidi lati ni igbona topari nitoripe ko si ona kankan ti adapo alegbogi tikojona ko ni wa.
- Igbana tabi ijona tikopari n sele ti opoiye oksijini to wa fun lilo ko to ninu ifesi alegbogi ohun. O si se e se ki iye oksijini toto o wa sugbon ona ti ijona na n sele ko gba laaye ki gbogbo oksijini ibe o se e lo.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |