Ààlọ́ oooooo

Ààlọ́

Ààló yìí dá lórí Ìjàpá àti ẹyẹ Àdàbà[1].

Gẹ́gẹ́ bí a se mọ pé alágàbàgebè ni Ìjàpá, olè àti ọkànjúwà ni pẹ̀lú. Ní ayé àtijó , Ìjàpá àti àdàbà jọ ń se ọ̀rẹ́ . Àdàbà ní ẹṣin kan tó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní nǹkankan. Ìjàpá ronú lọ́jọ́ kan, ó sì gbèrò bí yóó ti se pa ẹṣin Àdàbà . Ó rí pé Àdàbà gbayì láàrin àwùjọ èyí tí kò dùn mọ́ Ìjàpá nínú. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan Ìjàpá dá ọgbọ́n àlùmọkóróyí, ó pa ẹṣin Àdàbà . Àdàbà kò kúkú bínú síi kíkú tí ẹṣin rẹ kú . Ohun tí ó se ni pé ó gé ori ẹṣin náà ó bòó mọ́lẹ̀ , o wá fi ojú ẹṣin síta ki ènìyàn le máa rí í dáadáa . Bí Ìjàpá tí ń lọ lo ń rí ojú ẹṣin tó yo síta . Eléyìí yàá lẹ́nu , kíá ó gbéra ó di ilé oba, nígbà tí ó dé ààfin , ó sọ fun ọba pé òun ti rí ibi ti ilè gbé lójú . Eléyìí ya ọba lénu ,ó sì tún bi Ìjàpá bóyá ohun tí ó sọ dáa lójú . Ìjàpá ní ó dá òun lójú , ó sì tún fi dá ọba lójú wípé kí ọba yan àwọn ẹmẹ̀wà rẹ pé kí àwọn lọ wò ibi tí ilè gbé lójú. Ìjàpá ló síwájú tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní i korin báyìí pé[2];

ORIN ÀÀLỌ́

Ìjàpá ----------------------------------Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú

Agberin-------------------------------Ilẹ̀

Ìjàpá ----------------------------------Moti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú

Agberin ------------------------------Ilẹ̀

Báyìí ni gbogbo wọn ń dà rẹìrẹì lo sí ibi tí ilè gbé lójú. Bí Àdàbà se gbó ohun tí Ìjàpá se yìí ni ó sáré lọ si ibi tí o bo orí ẹṣin rẹ sí tí ò sì wu kúrò nibẹ lọ sí ibòmíràn kí àwọn ẹmẹ̀wà ọba tó dé ibè ,Nígbà tí ọba , ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ dé ibi tí Ìjàpá wí ,wọn kò rí nǹkankan , ni Ìjàpá bá bẹ̀rẹ̀ sí tú ilẹ̀ Kiri títí kòri ojú kankan, ìgbà yìí ni ọba bínú gidigidi pé Ìjàpá pa irú irọ tí ó tó báyìí àti pé ó tún da òun láàmú láti wá wò ohun tí kò si níbè . kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọn o ti ojú Ìjàpá yọ idà , kí wọn sì ti ẹyìn kìí bo akọ . Eléyìí jásí pé wọn paá. Báyìí ni ijapa fi ìlara pa ara rẹ .

Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLỌ́

Ààlọ́ yìí kó wa pé kí á ma maa se ìlara ọmọlàkejì , ká jẹ kí ohun tí a bá ní tẹ wa lọ́run.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  2. https://yorubafolktales.wordpress.com/


Ẹ̀ka:Aalo, Yoruba Folklores