Ìjàpá kó gbogbo ọgbọ́n Ayé sínú kèǹgbè

Apààlọ́ :Ààlọ́ o!

Agbe Ààlọ́ :Ààlọ̀!

Apààlọ́ : Ààlọ́ mí dá gbà-á, ó dá gbò-ó, ó dá fìrìgbagbóò, o dálérí Ìjàpá, Tìrókò, ọkọ Yáńníbo. Nígbà kan, Ìjàpá rò ó nínú ara rẹ̀ pé kí òun kó gbogbo ọgbọ́n ayé jọ pamó s'íbí kan kí òun wá di alákòóso rẹ̀, nitori Ìjàpá je ẹranko to ni ọgbọ́n èwé oríṣiríṣi lọ́wọ́ tó sì fẹ́ kí gbogbo ènìyàn mo. Ó fẹ́ di olókìkí àti gbajúgbajà látàrí bee. Ìjàpá wa akèrègbè, ó rìn láti ìlú rẹ̀ sí òmíràn káàkiri láti wá gbogbo ọgbọ́n ayé jo. Ó kó wọn sínú akèrègbè. Nígbàtí ó ṣe, o padà si ìlú rẹ̀, ó wá ọkùn tí ó nípòn láti fi so akèrègbè náà. O gbìyànjú láti gbe akèrègbè náà gun igi ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú rẹ̀ láti àárọ̀ títí oòrùn fi wọ̀ pàbó ló já si. Níbití ó ti ń se kìràkìtà ni ọdẹ kan ti rí i, ó sì bií pé kí ló fẹ́ ṣe: Ìjàpá kẹ́jọ́ o rò bí ó ṣe kó ọgbọ́n ayé jo sínú akèrègbè tí ó fẹ́ gbe gun igi láti le di alákóso ọgbọ̀n ayé.

Orin Ààlọ́

àtúnṣe

Ẹ̀kọ́ Ààlọ́

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe