Ìjàpá lọ jẹ àsè ní ilé Àdán

Ìfáàrà àtúnṣe

Ní ìgbà láéláé, tí àwọn àròsọ fi yé wa wípé àwọn ẹranko a máa sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, Ìjàpá jẹ́ ẹranko tí ó kún fún ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ púpọ̀ púpọ̀. Ní akoko yi, itan sọ fun wa wipe ọrẹ timotimo ni Ijapa ati Àdán. Ijapa n gbe ilẹ, nigbati Adan n gbe ori igi kan lẹba ọsa. Ṣugbon iṣẹlẹ kan ṣẹ ni akoko yii laarin awọn mejeeji[1].

Ìtàn àtúnṣe

Ni igba iwasẹ, ti Ijapa ati Adan nṣe ọrẹ minu, Ijapa a maa pe Adan si ibi inawo gbogbo ti o ba nse, yala isọmọlorukọ, iṣile tabi irufẹ inawo yowu ti ko ba maa ṣe. Ṣugbon o n ka Ijapa lara wipe oun kii le lọ si ibi inawo yowu ti Adan ba n se nitori wipe Ijapa ko le fo debi wipe yoo de ile Adan lori igi.

Nigba ti ọrọ yii ka Ijapa lara, ninu ọgbọn ẹwẹ rẹ, o pinnu lati wa nkan ṣe si ohun ti o n dun lọkan. Ori kuku ba Ijapa ṣe, nitori wipe ohun ti Adan ti n woju Eledua fun lati ọjọ to ti pẹ wọle wẹrẹ. Ọmọbinrin ni iyawo Adan ti n bi ṣaaju asiko yii, ṣugbon Eledumare fi ọmọkunrin lanti ta a lọrẹ ni akoko yii. Inu Adan dun tobẹẹ gẹ, nitori naa, kuku-kẹkẹ isọmọlorukọ yii kàmọ̀nmọ̀n. Iroyin ipalẹmọ yii lo ta si Ijapa leti ti o fi pinnu wipe bo ṣe gbigbe, bo ṣe wiwọ, oun o de ile Adan lori igi lati wa nibi isọmoloruko naa[2].

Ijapa ọlọgbọn ẹ̀wẹ́ kuku ri ọgbọn ta si i. Ohun ti o ṣe ni wipe o lọ wa aṣọ alaari to jọju, o wa ranṣe pe Adan wipe ki o wa gbe ẹbun ti oun fẹ fun lati fi ba a yọ wipe o bi ọmọkunrin lanti. Nigbati Ijapa gburo wipe Adan ti n bọ wa gba ẹbun naa, o sọ fun Yannibo aya rẹ wipe ki o we oun mọ inu aṣọ naa ni idi eyi, nigbati Adan gbe aṣọ de ile rẹ lori igi, wuya ni Ijapa yọ si. Eleyi jọ Adan loju pupọpupọ o si wi fun Ijapa wipe oun gba wipe ọlọgbọn ẹwẹ ni nitootọ. Ijapa jẹ, o mu, o ranju bọnbọn nibi ase isọmọlorukọ naa. Odidi ọjọ mẹta gbako ni won fi ṣe ayẹyẹ naa. Ni igbati ọti tan, ti ọka ko si mọ, Ijapa wa ranti ile, o ku bi yoo ti ṣe dele.

Ijapa ro ninu ara rẹ wipe ọgbọn ni oun o tun ta lati ri wipe oun de ile, nitori ile koko ni ti agbe. Ijapa pe Adan, o ni ọrẹ mi, ṣe o ṣe akiyesi wipe a kere pupọ ju awọn ẹranko miran lọ, Adan da lohun wipe oun naa ti n ro. Ijapa ni àrùn lo fa o! Arun ọhun si wa ni idi gbogbo ẹranko, awọn ti o ba ti yọ ti wọn ni won n tobi bii Erin, Ẹfọn, Igala, ati bẹẹbẹẹ lọ, ni idi eyi, Adan ati Ijapa yoo ba ara wọn yọ arun naa. Inu Adan dun o si imọnran ti Ijapa mu wa yii, ko tilẹ yiri rẹ wo ti o fi gba a.

Ijapa ree, igba ti o wa ni idi rẹ, ti o ba fi mu nkan, ko si ẹni ti o le fa a yọ. Kẹrẹ ti Adan ti ọwọ bọ idi rẹ ni o fi igba idi rẹ mu ṣikun, Adan fa ọwọ rẹ yọ ti ni idi Ijapa. O kigbe titi ṣugbọn Ijapa ko ṣi idi rẹ debi pe Adan yoo ri ọwọ rẹ yọ pada. Ijapa ba ṣe oju paiko lo sọ fun Adan pe ti ko ba gbe oun pada si ile oun ni isalẹ, a jẹ wipe ọwọ Adan ge danu nuu. Bayi ni o di dandan ki Adan gbe Ijapa pada si ile rẹ ni isalẹ igi lati ile Adan ti o wa lori igi.

Ẹkọ Inú Ààlọ́ àtúnṣe

  • Ki a ma maa gba ọrọ lai kọkọ yẹ wo
  • Ti ohùn eniyan kan ba dun mọnranmọnran ki a maa lo ọgbọn inu wa
  • Ki a ṣọra fun ọrẹ ti iwanwara rẹ ba ti pọ ju

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://dokumen.tips/documents/akojopo-alo-ijapa-babalola?page=11