Ìjàpá lọ jẹun l'ọ̀dọ̀ Ìyá Ajá

ÀÀLÓ ÌJÀPÁ ÀTI AJÁ àtúnṣe

Apààlọ́ :Ààlọ́ o!

Agbe Ààlọ́ :Ààlọ̀!

Apààlọ́: Ààlọ́ mí dá gbà-á, ó dá gbò-ó, ó dá fìrìgbagbóò, o dálérí Ìjàpá àti Ajá[1].

Ní àtijọ́, ní ìlú Ìjàpá, ìyàn mú gan-an ní, ìṣe àgbẹ̀ ni olúkúlùkù ń se. Àwọn ìyàwó kò ní ìṣe míràn àfi kí wọ́n tẹ̀le oko wọn lọ sóko fún ìrànlọ́wọ́. Bí òjò kò bá ti rọ̀ tabi esú je ǹkan ọ̀gbìn, ìyàn yóò bẹ́ ṣílẹ̀ nìyẹn.

Ìyàn kan bẹ́ ṣílẹ̀ ní ìlú Ìjàpá,ti gbogbo eranko nínú ìlú bẹ̀rẹ̀ sí nku lọ́kọ̀kan, èèjejì lọ́mọdé àti àgbà. Wọ́n mú owó dání ṣùgbọ́n won kò rí oúnjẹ ra bẹ́ẹ̀ni òjò kọ̀ kò rọ̀.

Kìnnìún tí ṣe ọba won pe ìgbìmọ̀ rẹ̀ jọ fún àpérò ki ìyàn má baà run gbogbo wọn tan. Won fẹnu kò sí pé kí àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fa ìyá won ṣílẹ̀ fún pípa jẹ, ó sàn kí arúgbó kú ju ọ̀dọ́ lọ[2].

Orin Ààlọ́ àtúnṣe

Kínìnrín j'okùn ṣílẹ̀ o,

Àlùjanjankíjan,

Kínìnrín j'okùn ṣílẹ̀ o,

Àlùjanjankíjan,

Erin pa yèyé rẹ̀ jẹ,

Àlùjanjankíjan,

Ẹfọ̀n pa yèyé rẹ̀ jẹ,

Àlùjanjankíjan

Gbogb'eranko pa yèyé wọn jẹ,

Ajá nìkan ló kù o,

Kinirin j'okùn ṣílẹ̀ o.

Àlùjanjankíjan,



Ẹ̀kọ́ Ààlọ́ àtúnṣe

- kí á má tú àṣírí tí wọ́n bá fi sí wa lọ́wọ́

- Kí á má dalẹ̀ ọ̀rẹ́.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  2. https://yorubafolktales.wordpress.com/


Ẹ̀ka:Aalo, Yoruba Folklores