Ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì
Fáwẹ́lì kìí kàn sà dédé jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ ọlọ́pọ̀ sílébù, wọ́n ní ètò ìjẹyọpọ̀ wọn. Àwọn fáwẹ́lì kan kìí jẹyọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan. Ohun gan-an tí a fẹ́ gbé yẹ̀wò ní apá yìí nìyí. Bátánì tí a ó tẹ̀lé nìyí; bí sílébù àkọ́kọ́ bá jẹ́ Fáwẹ́lì tí sílébù kejì sì jẹ́ Kọ́nsónáǹtì àti Fáwẹ́lì tí a lè ṣe ìgékúrú rẹ̀ báyìí: F1 – KF2.[1]
Báyìí ni ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì náà ṣe máa ń rí ní èdè Yorùbá:
Bí fáwẹ́lì [i] bá wà ní F1 gbogbo fáwẹ́lì èdè Yorùbá yòókù ni wọ́n lè wà ní F2. Àwọn fáwẹ̀lì bí i: a, e, ẹ, i, o, ọ, u, in, ẹn, ọn, an, àti un nínú ọ̀rọ̀ bí i
Ìlà, ilé, ìlẹ̀, ìdí, ihò, ìjọ, ìlù, ìpín, ìyẹn, ifọ́n, iyán, inú
Bí fáwẹ́lì [a] bá jẹyọ ni F1 gbogbo fáwẹ́lì èdè Yorùbá ni ó lè jẹyọ ni F2 (a, e, ẹ, i, o, ọ, u, in, ọn, an, àti un) àyafi fáwẹ́lì ẹn nínú àwọn ọ̀rọ̀ bí i:
Aya, àlè, alẹ́, àdí, àdó, akọ, adú, akin, àpọ́n, àyàn, àmù ṣùgbọ́n kò sí ọ̀rọ̀ bí i *ayẹn ní èdè Yorùbá.
Bí fáwẹ́lì [e] bá wà ní ipò F1, àwọn wọ̀nyí ni fáwẹ́lì tí ó lè wà ní ipò F2, i, e, o, u, in, un nínú àwọn ọ̀rọ̀ bí i:
ebi, èdè, ètò, eku, egbin, egúngún
A ó ṣàkíyèsí pé bí fáwẹ́lì [e] bá wà ní ipò F1 kò lè jẹyọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn fámẹ́lì bí i, ẹ, ọ, a, àti ẹn ní ipò F2. Nítorí náà a kò lè rí ọ̀rọ̀ bí ìwọ̀nyí ní èdè Yorùbá
*epẹ̀, *elọ, *egbà, àti èpọn
Bí fáwẹ́lì [ẹ] bá wà ní ipò F1, àwọn wọ̀nyí ni àwọn fawẹ́lì tí wọ́n lè wà ní F2: i, ẹ, a, ọ, u, ọn, un nínú ọ̀rọ̀ bí i:
ẹbí, ẹ̀bẹ̀, ẹ̀pà, ẹ̀fọ́, ẹbu, ẹ̀fọn, ẹ̀bùn. Bí fáwẹ́lì [ẹ] bá wà ni ipò F1, àwọn fáwẹ́lì yìí kò le wà ní ipò F2: e, o, àti ẹn. Nítorí náà, awọn ọ̀rọ̀ bí i *ẹpe, *ẹbo àti *ẹ̀yẹn kò lè wáyé nínú èdè Yorùbá
Bí fáwẹ́lì [o] bá wà ní ipò F1, àwọn fáwẹ́lì yìí ni wọ́n lè wà ní ipò F2: i. e, o, u, in, un, nínú ọ̀rọ̀ bí i:
òbí, olè, òdo, olú, opìn, okùn
Àmọ́, àwọn fáwẹ́lì yìí: ẹ, ọ, a, ẹn, àti ọn kò lè wà ní ipò F2 bí fáwẹ́lì [o] bá wà ní ipò F1. Nítorí náà, a kò lè ní irú ọ̀rọ̀ báyìí: *òpẹ̀, *òbọ, *òpá, *òsàn, *obọn
Bí fáwẹ́lì [ọ] bá wà ní ipò F1, àwọn fáwẹ́lì tí ó lè wà ní ipò F2 ni: i, ẹ, a, ọ, in, ọn, àti un nínú ọ́rọ́ bí i:
ọtí, ọ̀lẹ, ọfà, ọ̀bọ, ọ̀kín, ọpọ́n, ọ̀bùn
àwọn fáwẹ́lì bí i: e, o, u, àti ẹn kò lè bá fáwẹ́lì [ọ] jẹyọpọ̀ ní ipò F2 bí ó bá wà ní F1. Nítorí náà, a kò lè ní ọ̀rọ̀ bí i: *ọbe, *ọpo, *ọko, *ọbù àti ọ̀yẹn
Àwọn Fáwẹ́lì tí Wọn ò le wà ní F1
Ó yẹ kí a ṣàlàyé ní kíkún pé, àwọn fáwẹ́lì èdè Yorùbá kan wà tí wọn kò lè wà ní ipò F1 nínú ọ̀rọ̀ ọlọ́pọ̀ sílébù gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn saájú. Àkọ́kọ́ tí a ó mẹ́nu ba ni fáwẹ́lì [u]. Nínú ẹ̀ka èdè àjùmọ̀lò, fáwẹ́lì [u] kìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ àyàfi àwọn ẹ̀ka èdè kan pàápàá ẹ̀ka èdè àrin gbùngùn gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ Awobùlúyì (1998) nínú èyí tí ẹ̀ka èdè Ìjẹ̀sà, Ifẹ̀ abbl jẹ ara wọn. Nínú irú ẹ̀ka èdè yìí ni a ti lè rí ọ̀rọ̀ bí i ulé, ùdí, ùkòkò abbl.
Àwọn fáwẹ́lì aránmú náà kìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá nítorí náà wọn kò lè jẹyọ ní F1. ẹ jẹ́ kí a wo ọ̀rọ̀ bí i:
*unfin, *ọnmọ̀, *indí abbl
Àmọ́ sá, ó yẹ kí a fi kún un pé, ó ṣe é ṣe kí a rí àwọn aránmú yìí kí wọ́n bẹ̀bẹ̀ ọ̀rọ̀ ayálò láàárín àwọn Yorùbá òde oní pàápàá àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n ti ní ìfarakínra pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì bí i: ìnsìpẹ́kítọ̀ (inspector), ẹ́ngínì (engine), indonésíà (indonesia) abbl. Nítorí náà, bí a bá ni àwọn fáwẹ́lì aránmú kò le bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè Yorùbá, ó yẹ kí a máa rántí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn Yorùbá tí wọ́n ti ní ìfarakínra pẹ̀lú èdè Gẹ́ẹ̀sì pàápàá ní ilé-ìwé. Ó ṣe é ṣe kí àwọn Yorùbá tí wọn kò ní ìfarakínra pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì pe àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ṣe àpẹẹrẹ wọn lókè bámìíràn (ìsìpẹ́kítọ̀, ẹgínnì, idonésíà). Kí ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìwòye Owólabí (2013) nípa òfin tí ó de ọ̀rọ̀ àyálò wọ inú èdè Yorùbá.
Àkíyèsí lórí Bátánì Ìjeyọpọ̀ Fawẹ́lì nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́pọ̀ Sílébù
Owólabí (2013:145) ṣe àwọn àkíyèsí yìí
Bátánì ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì fún fáwẹ́lì ‘e’ àti ‘o’ jẹ ọ̀kan-ùn nítorí pé iye fáwẹ́lì kan náà ni kò lè tẹ̀lé wọn
Bátánì ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì fún fáwẹ́lì ‘ẹ’ àti ‘ọ’ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ ọ̀kan-ùn nítorí pé fáwẹ́lì ‘u’ nìkan soso tí ó lè tẹ̀lé ‘ẹ’, ṣùgbọ́n tí kò tllé ‘ọ’ ni ó fa ìyàtọ̀ láàárín bátánì ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì fún àwọn fáwẹ́lì méjéèjì yìí.
Bátánì ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì fún fáwẹ́lì ‘i’ àti ‘a’ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ ọ̀kan-ùn nítorí pé fáwẹ́lì ‘ẹn’ nìkan soso tí ó lè tẹ̀lé ‘i’ ṣùgbọ́n tí kò tẹ̀lé ‘a’ ni ó fa ìyàtọ̀ láàárin bátánì ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì fún àwọn fáwẹ́lì méjéèjì yìí.
Bátánì ìjẹyọpọ̀ fáwẹ́lì fún fáwẹ́lì ‘u’ àti àwọn fáwẹ́lì aránmú ‘ẹn’, ‘ọn’, ‘in’, ‘un’, jẹ́ ọ̀kan-ùn nítorí pé kò sí èyíkéyìí nínú àwọn fáwẹ́lì wọ̀nyí tí ó lè jẹ yọ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́pọ̀ sílébù nínú èdè Yorùbá.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Details for: Fonoloji ati girama yoruba › Bamidele Olumilua University of Education, Science & Technology, Ikere-Ekiti catalog". Bamidele Olumilua University of Education, Science & Technology, Ikere-Ekiti catalog. Retrieved 2024-08-06.