Ìjọ Jéésù Lótìítọ́

Ìjọ Jéésù Lótìítọ́ ti a dá s’ílẹ̀ ní ìlú Beijing, Shaina ní ọdún 1917, jẹ́ ìjọ t’ó dá dúró nínú àwọn oní-pẹ́ntíkọ́stì. Ìjọ yìí faramọ́ ìkọ́ni “ọ̀kan soso l’Ọlọ́run”. Wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀kan l’Ọlọ́run àti pé Jésu jẹ́ Ọlọ́run. Ìjọ yìí kọ ìkọ́ni “mẹ́tal’ọ́kan” pé kò tọ́, kò sì dọ́gba láti s’àpèjúwe Ọlọ́run. Ìjọ gbà pé ìkọ́ni “mẹ́tal’ọ́kan” kò wá láti inú Bíbélì nìkan sùgbọ́n láti inú àwọn orísirísi àfikún lẹ́yin àkojo Bíbélì, èyí tí àwọn olùtèlé “ọ̀kan soso l’Ọlọ́run” kà sí èrò èniyàn lásán, tí kò ní àsẹ ìmísi Ọlọ́run bíi ti Bíbélì.

Ìjọ Jéésù Lótìítọ́ .

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kà á sí ìjọ àwọn ará Sháínà, “Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” lóde òní tí ó n tàn kálẹ̀ àgbáye bí a ti n wàásù ìhìnrere Jéésù kárí ayé. Iye àwọn olùtèlé “Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” jẹ́ ẹgbèrún lọ́nà ẹgbàá mẹ́jọ èniyàn ní orílẹ̀ kọ́ntínẹ́ntì mẹ́fà ní àgbáyé.

Akọkọ igbagbo

àtúnṣe
  1. Emi Mimo: Gbigba emimimo, aridaju nipa fifi ede titun soro, eleyi je idaniloju ipin wa ni ijoba orun.
  2. Iribomi: Iribomi jẹ́ ise fun irapada ese lati irandiran. Iribomi n waye ninu omi bi Odo, Okun tabi omi ti n san. Eni ti a ti se iribomi ti omi ati tie mi mimo no o n se iribomi yii fun elomiran ni oruko Olwa wa Jésù Kristi. Eni ti a n se iribomi fun gbodo je riri bo omi patapata pelu ori ti yio teriba sinu omi.
  3. Ise ti fifo ese: Ise ti fifo ese jẹ́ ki eniyan ni ipin pelu Jésù Kristi. O si jẹ́ ohun iranti wipe eniyan gbodo ni ife, ije-mimo, iteriba, idariji ati ise iranse. Gbogbo eniyan ti a ti ri bo omi ye ki a we ese re ni oruko Jesu Kristi. Ise ki onikaluku we ese ominikeji re jẹ́ ohun ti o ye ki o di sise nigba ti o ba to.
  4. Ounje ale Oluwa: Ounje ale Oluwa jẹ́ sise fun iranti iku Jesus Kristi Oluwa wa. O jẹ́ ki a jẹ́ alabapin ninu eran ara ati eje Oluwa wa lati jẹ́ alajopin ninu iye ayeraye ki a si ji dide ninu oku ní ojo keyin. A gbodo ma se eleyi ni gbogbo igba. Buredi ati omi eso ‘girepu’ ní a oo lo.
  5. Ojo Isinmi: Ojo Isinmi, Ojo keje ose (Satide), je ojo mimo ti Ọlọ́run ya si mimo. Ojo yi jẹ́ yiyasoto ni abe ore ofe Olorun fun iranti awon eda Ọlọ́run ati igbala won pelu Ireti Isinmi ayeraye ni aye ti n bowa.
  6. Jésù Kristi: Jésù Kristi, oro naa ti o di eran-ara, ku fun wa ni ori igi agbelebu fun irapada elese, a jii dide ní ojo keta, o goke re orun. Ohun nikan ni olugbala araye, eleda orun oun aye, Olorun otiti kan soso.
  7. Iwe mimo: Iwe mimo, ninu re ni a ri Majemu Lailai ati Majemu titun, imisi eleyi ti o wa lati odo Ọlọ́run, iwe ododo kan soso ati ilana tooto fun igbe aye kristieni.
  8. Igbala: Igbala jẹ́ ohun ti a fifunni nipa Ore ofe Ọlọ́run nipase Igbagbo. Onigbagbo gbodo fi ara tan emi-mimo lati lepa Ije mimo, lati bowo fun Olorun ati lati fe ohun eda Ọlọ́run.
  9. Ijo mimo Jésù: Ijo mimo Jésù, ifilole lati owo Jésù Kristi wa, nipase emi mimo ní akoko “ojo ikeyin” ni ipadabosipo ijo tooto ti igba awon aposteli.
  10. Ipadabo Jésù kriti: Ipadabo Jésù kriti yio sele ní ojo ikeyin nigba ti O ba sokale lati orun wa lati da aye ní ejo: olododo yio jogun iye ainipeku, nigbati awon eni buburu yio jogun iparun ayeraye.