Ìkún omi Mozambican ti ọdún 2007
Ìkún omi Mozambique tI ọdún 2007 bẹ̀rẹ̀ ní ìparí oṣù kejìlá ọdún 2006 nígbàtí ìdídò ti Cahora Bassa ti ṣan omi látara òjò ńlá ní Gúsù Âfíríkà. Ó burú si ní ọjọ́ kejìlélógún,oṣù Kejì,ọdún 2007, nígbàtí Ẹ̀ka kẹrin Cyclone Favio ṣe ilẹ̀ ní agbedeméjì ti Inhambane ; Àwọn alámọ̀dájú ti ń tọ́pa ìjì náà sọtẹ́lẹ̀ pé yóò burú sí ní àfonífojì Odò Zambezi. [1] Odò Zambezi fọ́ bèbè rẹ̀, ó sì ń ṣàn wọ àwọn agbègbè tó yí wọn ká ní Mozambique. Àwọn odò Chire ati Rivubue tún kún.
Àwọn èyàn 80,600 ló kúrò ní ilé wọn ní agbègbè Tete,Manica,Sofala àti Zambezia ní ọjọ́ kẹrìnlá,oṣù kejì.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Beatty, Sean. Tropical cyclone slams into flood-stricken Mozambique. BBC News, February 24, 2007