GBADAMOSI TEMITOPE THOMAS

ÌKỌ́NI: TEACHING

Kíní a mọ̀ sí ìkọ́ni?

Ìkọ́ni túmọ̀ si ìlànà ti àhún gbà láti fii òye hàn láti ìran kan dé òmíràn àti láti ènìyàn sí elòmíràn. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ìkọ́ni lèè túmọ̀ sí ìbáwí tàbí ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ ẹnití ó ju ẹni lọ. Àmọ́ ki a máa fi ọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀pọọlọ pa ejò, ìkọ́n tòní dá lórí ti Òye, Ìmọ̀ tàbí Èkó.

Tí bá ní kí a woo bi ìtàn ìkọ́ni sé bẹ̀rẹ̀, a máa tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ odún sẹ́yìn. Akòleè sọ pàtó ibi ti ìkóni ti bẹ̀rẹ̀, nítorí pé orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kàn àti àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn níbikíbi lóní ìlànà ti wọ́n ń gbá kọ́ àwọn ènìyàn tiwọn. Ṣùgbọ́n orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ bíi Gíríìsì (Greece) tí ìsirò ti bẹ̀rẹ̀, ilẹ Lárúbáwá (Arabia), ile isrẹẹli ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, wa nínú àwọn irú ènìyàn tí ó tayọ nínú ètò ìkọ́ni. Àmọ́ ètò ìkọ́ni bí a sè mọ̀ ti di àtọwọ́dọ́wọ́ débi wípé olúkúlùkù lóti gbàá ti wọ́n sì ti fi tún orílẹ̀ èdè wọn tò.

Bí a ti se ń kọ́ni se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwùjọ, bí ati se lèe kọ́ ọmọdé yàtọ̀ sí bí ati se lèe kọ́ ọ̀dọ́ lángba bẹ́ẹ̀ ni ti ọ̀dọ́ langba náà yàtọ̀ sí ti àgbàlàgbà. Gbogbo wa lamọ̀ wí pé ọmọdé a máa tètè kọ́ ẹ̀kọ́ láti ibi àwòrán, àwọ̀ àti àfihàn. Nítorí ìdí èyí, àwọn ìwé tí alákọ̀bẹ̀rẹ̀ bíi aláwìíyé dára púpọ̀ fún ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé.

Ẹ̀wẹ̀, tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí bá déé ilé ẹ̀kọ́ girama ìlànà kíkọ́ àti mímọ̀ wọn yóò ti yàtọ̀ díẹ̀ sí ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀. Ní pele yìí, a óò tí máa fi yé wọn bá wọ́n se leè fi ọwọ́ ara wọn see àwọn ohun tí wọ́n ń kó wọn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn oo ti máa gbáradì fún ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ní ilé ẹ̀kọ́ girama ẹ̀wẹ̀, àwọn ohun ti àwọn akẹ́kọ̀ óò máa há sórí – àkósórí àwọn akẹ́kọ̀ yóò din kù, yàtọ̀ sí tii ilé ẹ̀kọ́ ‘Jéléósimi’.

Ǹjẹ́ tí abá dé ilé ẹ̀kọ́ gíga, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàtọ̀ ni yóò ti wà nínú bi ase ń kọ́ni. Ilé ẹ̀kọ́ gíga ilé ọgbọ́n, ilé ẹ̀kọ́ gíga ilé òmìnira. Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga akẹ́kọ̀ ní àǹfààní lati se ohun tówùú nígbà ti ó bá fẹ́ tí kòsì olùkọ́ tí yóò yẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ wò. Ìkọ́ni nílé ẹ̀kọ̣́ gíga yàtọ̀ gédégédé sí ti ilé ẹ̀kọ́ girama tàbí alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

Ní ilé ẹ̀kó gíga, akẹ́kọ̀ ló nílò láti se isẹ́ jù, nítorí péé; ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, olùkọ́ yóò kàn wá láti tọ́ akẹ́kọ̀ sọ́nà ni, akẹ́kọ̀ ni yóò se ọ̀pọ̀lọpọ̀ isẹ́ fún ra rẹ̀.

Ìkọ́ni ni orílẹ̀-èdè yi ti dojú kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro tí ósì ti ń se àkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé àti ìdàgbà sókè ilẹ̀ yí. Tí abá ni kí áwòó láti ìgbà ìwásẹ̀ fún àpẹẹrẹ, ètò ìkọ́ni dára ni ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀, èdè Yorùbá ni afi hún kọ́ akẹ́kọ̀ láti ilẹ̀ kí àtó kii èdè òmíràn bọ̀ọ́, àmọ́ ni báyìí èdè gẹ̀ẹ́sì ni afi ń kọ́ akẹ́kọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn si ń sọ èdè Yorùbá nílé. Èyí lómú kí ó jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò leè sọ èdè Yorùbá kó já gaara láì má fii èdè gẹ̀ẹ́sì kọ̀ọ̀kan bọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò sì leè sọ èdè gẹ̀ẹ́sì dáradára. Ọ̀rọ̀ wa dàbíi “ẹni tí ófi àdá pa ìkún, ikún sálọ àda tún sọnù”.

Kí ń tó fí gègéèmi sílẹ̀, gbogbo wa lamọ̀ wí pé ni àìsí ìkọ́ni kòleè sí ìmọ̀, ni àìsí ìmọ̀ láti ìran kan dé òmíràn; kò leè sí ìdàgbà sókè, ni àìsí ìdàgbà sókè ẹ̀wẹ̀, kò leè sí ìlosíwájú, ìlú tí kò bá sì ní ìlosíwájú ti setán láti parun ni. Fún ìdí èyí a óò ri péé ìkọ́ni jẹ́ ohun kan gbógì tí a kò leè fi seré ní àwùjọọ wa.


Ẹ̀kọ́ dára púpọ̀

Ẹ̀kọ́ lóni ayé táawà yi sẹ́

Ẹ̀kọ́ lóhún gbéni dépò gíga

Ẹ̀kọ́ lóhún gbéni dépò ọlá

Ẹ̀kọ́ dára púpọ

Ẹ̀kọ́ lóni ayé tí awà yí sẹ́.

ÌTỌ́KASÍ (REFERENCE)

i. D.F. Odunjọ - ‘Alawìye Apa keta’

ii. B. Onibonoje – ‘Iwe Ikọni Yorùbá

iii. White Shear – ‘ Teaching skills’