Ìlù Sàtọ́
Ìlù Sátọ́ jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ pàtàkì ní ìlú Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Ó jẹ́ ìlú kan tí ó gbajúmọ̀ jùlọ láwùjọ àwọn ẹ̀yà Ògù ní Badagry. Ìlú Sátọ́ jẹ́ ìlù méjì tí ó tóbi tí gíga rẹ̀ ju Ènìyàn lọ ní ìdúró. Ó jẹ́ ìlú tí wọ́n fi ń ré ibi dànù láyé àtijó. Ṣùgbọ́n lóde òní, wọ́n tí ń lu ìlù Sátọ́ níbi àwọn ayẹyẹ pàtàkì. [1] Ìlù Sátọ́ jẹ́ ìlú tí ó ga jùlọ ní àgbáyé. [2]
Pàtàkì Ìlù Sátọ́
àtúnṣeSátọ́ jẹ́ ìlú tí wọ́n fi ń ṣe ètùtù láyé àtijó. Wọ́n gbàgbọ́ pé dídún ìlù Sátọ́ máa ń ré ibi dànù. Àwọn onílù yìí gbàgbọ́ pé ìró ìlú yìí máa ń jẹ́ kí àwọn èmi burúkú tí ó máa ń fa àjàkálẹ̀ àrùn. Láyé àtijó, ó ṣọ̀wọ́n kí ìlù Sátọ́ tó jáde, àyàfi tí wọ́n bá ní ètùtù tàbí ọdún ìbílẹ̀ kan láti ṣe, ṣùgbọ́n lóde òní, wọ́n tí ń lu ìlú Sátọ́ ní ibi ayẹyẹ lóríṣiríṣi.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "In Badagry, Sato drums hold life, communal prosperity » The South West » Tribune Online". Tribune Online. 2018-09-25. Retrieved 2019-11-30.
- ↑ "‘World’s tallest drum is my dream’ - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2013-03-05. Retrieved 2019-11-30.
- ↑ Type, Hotel (2019-11-30). "The Sato Drum Statue. A very tall sacred drum that wades off the stillbirth evil spirit when bea - Picture of Badagry Slave Museum and Black History Museum". TripAdvisor. Retrieved 2019-11-30.