Ìpalára
Ìpalára jẹ́ ìṣeni-láída búburú ní ara, tí ó le ba ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ tàbí wíwà láyé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀.[1] A tún le ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbanilára jẹ́ tí ó le dín iyì ohun kù, bùrẹ́wà ohun bẹ́ẹ̀, àìlèṣe rẹ̀, tàbí kí ó sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ di aláìpé.[2][3] Ní ayé òde-òní, èrò yìí túmọ̀ sí ohun tí ó burú jáì.[1][4]
Àká-ọ̀rọ̀
àtúnṣeNí 2019, Michael H. Stone, Gary Brucato, àti Ann Burgess dábàá ìlànà àìgbẹ̀fẹ̀ láti le ṣèyàtọ̀ "ìpalára" àti "ìyakúrò", nítorí gbígbé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí síra máa ń sábà wáyé. Wọ́n sì dábàá pé ìyakúrò níṣe pẹ̀lú "ìyọkúrò pátápátá, lọ́nàkọ́nà tó bá gbà, apá ńlá kan lára alàyè tàbí òkú, ní pàtó, orí irú ẹni tàbí òkú bẹ́ẹ̀, apá, ọwọ́, ìbàdí, ẹsẹ̀, tàbí àtẹ́lẹ́ẹsẹ̀". Nígbà tí ìpalára lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀ níṣe pẹ̀lú "ìyọkúrò tàbí ìbàjẹ́ àìní-àtúnṣe lọ́nàkọnà àwọn ìpín ara ńláńlá ènìyàn tó wà láàyè tàbí tó ti kú. Ó le jẹ́ yíyọ kóró-ẹpọ̀n, àwọn ẹ̀yà ara inú, tàbí yíya àwọn". Nípasẹ̀ àwọn ìlànà wọ̀nyí, yíyọ ọwọ́ ènìyàn pátápátá máa túmọ̀ sí "ìyọkúrò", nígbà tí ṣíṣe ìjàmbá fún ìka-ọwọ́ yóò jẹ́ ìpalára, tí yíyọ gbogbo òkè ara títí dé ẹsẹ̀ yóò jẹ́ ìyakúrò, nígbà tí yíyọ tàbí ṣíṣe ìjàmbá fún ọyàn tàbí àwọn ẹ̀ya-ara mìíràn yóò jẹ́ ìpalára.
Ìpalára Gẹ́gẹ́ bí i Ìfiyajẹ Ènìyàn
àtúnṣeJames Gavin ti Douglas, Lanarkshire jẹ́ èyí tí etí rẹ̀ di gígé sọnù nítorí ó kọ̀ láti ṣe ìkọsílẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn rẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè Japan, Gonsalo Garcia àti àwọn ará rẹ̀ jìyà irú ìfìyàjẹ yìí.
Bákan náà, ní agbègbè-agbára àwọn Kólónì Mẹ́tàlá, fún ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké bí i tí ènìyàn kan bá jí ẹlẹ́dẹ̀ gbé le fà kí wọ́n la etí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n ge bọ́, ìgbà mìíràn sì wà tí ìfìyàjẹ fún ẹni tó bá ń ṣe àtúnrọ àwọn ohun ni láti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú epo tó bá wà lórí iná, àpẹẹrẹ ìpalára ìwọ̀-oòrùn nìyí.[5]
Síwájú sí i, òmìnira kò díwọ́ ìṣèdájọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kù. Bí àpẹẹrẹ, ní agbègbè Gúúsù-mọ́-ìlà-oòrun (ilẹ̀ Tennessee), àpẹẹrẹ ìdájọ́ àìfilélẹ̀ kíkan lábẹ́ Cumberland Compact wáyé ní 1793 nígbàtí Adájọ́ John McNairy ṣe ìdájọ fún olè ẹṣin àkọ́kọ́, John mcKain Jr., pé kí wọ́n só orí àti ọwọ́ rẹ̀ mọ́ igi ẹlẹ́wọ̀n kan fún wákàtí kan fún ẹgba mọ́kàdínlógójì, wọ́n sì tún gé etí rẹ̀ méjèèjì kúrò, lẹ́yìn náà ni wọ́n kọ lẹ́tà "H" àti "T" sí ẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjèèjì.
Gégé ahọ́n burú jáì, ṣùgbọ́n kò wọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí i oríṣi ìpalára àti ìfìyàjẹ.[6] Nítorí ahọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun-èlò ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ dídà yóò pọ̀ olùjìyà bẹ́ẹ̀ sì le tipa rẹ̀ kú.
Nebahne Yohannes, tí ó jẹ́ olùgbẹjọ́ aláìyege fún olùjọba ìtẹ́ Ethiopia jẹ́ èyí tí etí rẹ̀ méjèèjì àti imú rẹ̀ di gígé sọnù, lẹ́yìn náà ni wọ́n tu sílẹ̀.Àmúlò irúfẹ́ ìpalára fún àwọn olùgbẹjọ́ aláìyege ìtẹ́ ọba yìí ti wà láti àìmọye ọdún sẹ́yìn ní agbègbè àárín-ìlà-oòrùn. Nítorí láti tayọ gẹ́gẹ́ bí Ọba láyé ìgbà náà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ wà ní pípé. Irú ìpalára àwọn ẹlẹ́ṣẹ́ yìí máań wáyé kí ó le jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Pitts, Victoria (2003). In the Flesh: The Cultural Politics of Body Modification. Palgrave Macmillan. pp. 25. ISBN 9781403979438.
- ↑ Staff (October 7, 2022). "Definition of Mutilate". Merriam-Webster (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved October 27, 2022.
- ↑ Staff (November 14, 2022). "Mutilation: Definition". Encyclopædia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved November 14, 2022.
- ↑ Inckle, Kay (2007). Writing on the Body? Thinking Through Gendered Embodiment and Marked Flesh. Cambridge Scholars Publishing. pp. Preface: X, 20. ISBN 9781443808729.
- ↑ Garraty, John A. (2003) Historical Viewpoints. New York City, New York: Addison Wesley Longman, Inc.
- ↑ "A History of Punishments". Localhistories.org. Retrieved 8 December 2014.