Ìrànwọ́ 1: Báwo lẹ ṣe lè dá àyọkà/ojú-ewé

Ìṣẹ̀dá ojú-ewé ojú-ewé jẹ́ ojú-ìwé tí a lè kà láti ní ìmọ̀,ọgbọ́n àti òye yálà láti kọ́ tàbí ṣe àlékún lórí ohun kan tàbí òmíràn lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Àkíyésí

àtúnṣe

Àwọn ohun tí a ní lá ti ní ṣáájú kí a tó dá àyọkà kankan ni:

  • A ní láti ní ìmọ̀ àmọ̀dájú lórí àyọkà tí a fẹ́ dá dára dára.
  • A ní láti nímọ̀ nípa èdè tí a fẹ́ fi gbé àyọkà wa sílẹ̀ dára dára.
  • A ní láti ní orúkọ oníṣẹ́ tí yòó ma ṣe ònkà àti àtòjọ àwọn àfikún wa lọ́kan ò jọ̀kan tí a bá ṣe.
  • àyọkà ojú-ewé tí a fẹ̀ ṣẹ̀dá gbọ́dọ̀ jẹ́ mọ́ ohun tí jẹ́ ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí a lè rí ìtọ́ka kan tàbí méjì lórí rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-ayélujára.
  • Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àkórí tí ó gbogbo ènìyàn mọ̀ nípa rẹ̀ láwùjọ rẹ ṣùgbọ́n tí kó sí àkọsílẹ̀ fun lórí ìkànì yí.

Bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ojú-ewé

àtúnṣe

Ọ̀nà méjì ni a lè gbà ṣẹ̀dá ojú-ewé sí orí Wikipẹ́día Yorùbá. Àkọ́kọ́ ni lílo ìlanà Àtọwọ́dá, nígba tí ékejì jẹ́ ìlanà Ògbufọ.

  1. Ìlànà Àtọwọ́dá èyí ni kí á ṣe àwárí àkòrí àyọkà tí a fẹ́ ṣẹ̀dá lórí ìkànì Yo Wiki nípa títẹ https://yo.wikipedia.org tí yóò sì gbé wa wá sí ojú-ewé àkọ́kọ́. Lẹ́yìn èyí, a ó kọ àkórí àyọkà tí a fẹ́ ṣẹ̀dá sínú àpótí onígun mẹ́rin tí wọ́n kọ Ṣàwárí nínú Wikipẹ́día tí a ó sì ṣàwárí rẹ̀. Bí àyọkà wa bá wá pẹ̀lú àwọ̀ 'Búlúù', á jẹ́ wípé irúfẹ́ àkòrí àyọkà yẹn ti jẹ́ dídá sí orí Yorùbá Wikipẹ́día nìyẹ̀n, a kò sì lè tun ṣẹ́dá mọ́. Àmọ́, bí àkòrí àyọkà tí a fẹ́ dá tí a sì ṣàwárí rẹ̀ bá wá pẹ̀lú àwọ̀ 'Pupa', á jẹ́ wípé irúfẹ́ àkòrí àyọkà bẹ́ẹ̀ kò tíì jẹ́ dídá sílẹ̀ lórí Yorùbá Wikipẹ́día. Fúndí èyí, ẹ ó tẹ èsì àwárkprí yín pupa náà, yíò sì gbé yín lọ sí ojú-ewé mìíràn tí ẹ ti lè ṣe àkọsílẹ̀ pẹ̀lú ilà tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n ń pè ní (Cursor) tó ń lọ tó ń bọ̀.

Ààtò ati ìgbékalẹ̀ àyọkà (formating)

àtúnṣe

Kí àyọkà wa ó lè jọjú, a ní láti tẹ̀lé àwọn ìlànà ààtò yí:

  • lílo àmì ( ' ) àpọ́sítírọ́fì. A ma ń lo àmì yí láti fi ṣàdáyanrí àkòrí àyọkà wa nípa kíkọ àmì yí mẹ́ta sí apá òsì àti mẹ́ta sí apá ọ̀tún, kí a tó kọ àkòrí àyọkà sáàrín rẹ̀ báyìí ( ). Bí a bá sì fẹ́ kí àkòrí yí rí báyí kí ó sì tún dẹ̀gbẹ́ sápá ọ̀tún, a ó lo àmì yí márùn ún báyí ( ) .

Àpẹẹrẹ: kíní Ewúrẹ́ jẹ́ ẹran ilé. Àpẹẹrẹ kejì Ewúrẹ́ jẹ́ ẹran ilé . A ó ṣàkíyèsí wípé (Ewúrẹ́) àkòrí àyọkà lówúra ju àwọn ọ̀rọ̀ tó kù lọ. Lẹ́yìn èyí, a ó ṣe ìfáàrà sí obun tí ewúrẹ́ jẹ́. Bí a bá tún ní ohun kan mìíràn láti sọ nípa ewúrẹ́ bíi : Ewúrẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹràn ọ̀sìn Ilé, orísi ewúrẹ́ (akọ tabí abo), bí wọ́n ṣe ń bímọ, óúnjẹ tí wọ́n fẹ̀ràn, ìwà wọn àti bẹ́bẹ́ lọ. A ó ṣe àgbékalẹ̀ àwọn amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ àkòrí yí nípa lílo àmì = méjì sápá ọ̀tún méjì sápá òsì báyìí == ==. Àpẹẹrẹ: = = Ewúrẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọ̀sìn ilé = = Àkíyèsí: a kò sú àwọn àmì yí mọ́ra wọn nítorí kí ó lè yé wa. Bí ẹ bá fẹ́ lo tiyín, kí ẹ sun mọ́ra wọn kí ó lè rí báyí:

Ewúrẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọ̀sìn ilé

àtúnṣe

Bí a bá fẹ́ kí (Ewúrẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹran ilé) náà ó lówúra, a ó ṣe àmì yẹn ní mẹ́ta lósì === mẹ́ta lọ́tún === . Báyí ni a ó ṣe fún àwọn amúgbálẹ́gbẹ́ àkòrí tína mẹnu bà lókètó kù.

Oríṣi Ewúrẹ́ tó wà

àtúnṣe

==Bí wọ́n ṣe ń bímọ== àti bbl.

Bí a bá ṣèyí tán, tí a sì fẹ́ fi iṣẹ́ wa pamọ́, a gbọfọ̀ kádí àyọkà wa pẹ́lú ÀWỌN ÌTỌ́KASÍ. A ó kọ ọ̀rọ̀ sínú àmì = bí a ti ṣe fún àwọn tókù. Àpẹẹrẹ ==Àwọn Ìtọ́kasí==. Aó ma mẹ́nu ba ìtọ́kasí àti ìdárúkọ àyọkà nínú àyọkà nínú ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ mìíràn.