Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje

Irinkerindo ninu Igbo Elegbeje ni oruko iwe ti D.O. Fagunwa ko. Ìrìnkèrindò ni ìwé ìtàn-àròsọ yìí dá lé lórí. Ìwé yìí ni D. O. Fagunwa pè ní Apá Kẹ́ta Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Nínú Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje, a ìbẹ̀rẹ̀ ìrììnàjò sí òkè ìrònú, alábàá pàdé ẹlẹ́gbára, ìtàn òmùgọ́diméjì àti Òmùgọ́dimẹ́ta ìtàn wèrédìran àti ìgbéyàwó Ìrìnkèrindò

Irinkerindo wọle de Ojú-Ìwé 1-15

àtúnṣe

Aiyé kún fún ibùgbé ìyanu, ọba bí Ọlọ́rûn kò sí, Olódùmarè ní ńṣe alákǒso ohun gbogbo tí ńbẹ ní òde aiyé àti òde ọ̀run, ìyanu ní aiyé pàápàá jẹ́: aiyé kún fún ènìà ẹlẹ́sẹ̀ méji ati eranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin,ejò afàiyàfà àti ẹja tí ńkákìiri inú omi, ẹiyẹ tí nkọrin bí fèrè àti alágẹmọ tí Olódùmarè wọ̀ ní onírúnrú asọ.Òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, oòrùn àti òsùpá, àwọ̀sánmọ̀ àti erùpẹ̀ ilẹ̀,gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ìyanu.Bákannáà ní ọ̀rọ̀ sìsọ lásán yìí jẹ́ ìyanu, èyítí, mo sì gbọ́ ní ìjọ́sí ni mo ní kí nbá yín sọ lónǐ, ẹ̀nyin ọmọ ènìà..

Ìbẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò sí òkè ìrònú tí mbẹ nínú igbó ẹlẹ́gbẹ́jẹ̀ Ojú-Ìwé 16-30

àtúnṣe

Ní òwúrọ̀ ọjọ keji, ko pẹ púpò ti mò lọ kí àlejò wà yi tán tí nóẉn fi wí fún mi pé onjẹ tí ṣetán, gbogbo wà lọ sí tábílì, a jẹun. Ìyàlẹ́nu l’o jẹ fún mi pe bi o tilẹ̀ ti jẹ́ pé nkò sọ fún púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi nípa okùnrin na tó wọnni, síbẹ̀ ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀nìà l’o ti gbọ́ nípa okùnrin na, kí o sí tó di pe a jẹun àrọ̀ tán lọ́jọ́ na àwọn ẹ̀nìà tí rọ́ de ilé wa. Bí a tí jẹun tán ní mò ko àwọn ohun ìkọ̀wé jáde tí mò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, on na sí bẹ̀rẹ̀sí ọ̀rọ̀ ísọ ní: ...

Alabapade ẹlẹgbara Ojú-Ìwé 31-37

àtúnṣe

“Lẹhin eyi, a kọju si ọn Igbo Elegbeje, a nlọ. A ko ri nkan abami kan ti o ṣe pataki fun ọjọ diẹ o to bi ọjọ mẹta ti a ti sin Gọngọṣutakiti ki o to dip e nkan miran tun de ba ni, bayi ni:

“Bi a ti de ibi kan bayi ti o tẹju diẹ ti a duro ti a jẹun tan ni a dede gbọ ariwo ogunlọgọ awọn ọmọde ni apa ọna ibiti a nlọ ti ẉon nke bọ lapa ọdọ wa. Aiya mi ja pupọ nitori igbe yi nitori mo nbẹru ki ó má ba jẹ iwin buruku ti okiki rẹ̀ ti kan jakejado ode aiye ti a npe ni Ẹlẹgbara. Iwin buruku ni, bi ò ba nbọ awọn ọmọ rẹ̀ ti a npe ni ọmọ Ẹlẹgbara ni o ma nṣaju ti noẉn ma nkede bibọ̀ rẹ̀ fun gbogbo ohun alaye. ...

Ilu awọn èdìdàrẹ́ ni ibiti omugọdimeji ti nṣe ọba wọn Ojú-Ìwé 38-48

àtúnṣe

“Nigbati a kuro ni ibiti awọn ẹranko wọnyi wà ti a tubọ rin diẹ siwaju a ri ọna kekere kan bayi ti o yà ba apa osi lọ, Nwọn kọ àkọlé kan si ìyànà na, nkan ti ẉon si kọ ni eyi: ‘Ilu awọn Èdìdàrẹ́ nibiti Omugọdimeji ti nṣe ọba wọn.’

“Akọle yi yà wa lẹnu a si yà si ọna na ki a ba lọ wo bi ibẹ ti ri. Nigbati a rin si iwaju diẹ, a bẹrẹsi wo ilu na ni ọkankan ṣugbọn ọna ti a ntọ̀ lọ tubọ ndi kekere si i afi bi ẹni pe enia ko ngbe ilu na ni, nigbati o sa pẹ ṣa, a yọ si ilu yi....

Omugọdimẹta g’ori oye ṣọpọnna gbe omugọdimeji lọ Ojú-Ìwé 49-54

àtúnṣe

Ibiti alejo mi sọrọ na fun mi mọ lọjọ ti a tun nkọwe na ni eyi, a ba da ọwọ duro lọjọ na, a ki awọn ti o wa gbọ ọrọ w ape ki noẉn ma lọ sile ki nwọn tun pada lọjọ keji.

Ko pẹ pupọ ti ilẹ ọjọ keji si mọ ti gbogbo enia tun fi nrọ wọ ile mi, igbati awa na si jẹun tan, alejo mi tun bẹrẹ o nba itan na lọ o ni:

“Ẹnyin ọrẹ mi, ibiti mo ba irohin na de lana ni iku Omugọdimeji. ...

Ẹbọra igberaga-ibanujẹ ati ahọndiwura iyawo rẹ̀ Ojú-Ìwé 55-59

àtúnṣe

“A kuro ní ilu awọn Edidarẹ lẹhin ti a ti gbe eti ibẹ fun odidi oṣu mẹta gbako, a kọ ori si ọna wa. Ẹ má jẹki eyi yà yin lẹnu pe a pẹ tobẹ̀ ni ilu kan ti a ko lọ si ibiti nwọ́n ran wa. Ọba papa ti fun wa ni aṣẹ bẹ ki a to kuro ni ile, o ti wi fun w ape bi a ba de ibikibi ti a ri i pe ohun ti a nfẹ ṣe yio gba ni to oṣu mẹfa tabi ju bẹ lọ ki a maṣe kanju, ki a ṣe e dada....

A fi oju wa ri ọrun apadi Ojú-Ìwé 60-70

àtúnṣe

“Bí a ti de ibikan ti o dakẹ minimini bayi, ti igbo ibẹ di ti o dudu mirinmirin ni a ri iwin kan ti o nbọ, o dabi ọba gan, igbati a si kọ ri i, a ke ‘Kabiyesi’, a ti gbagbe pe Aginju Baba-loriṣa ni wà, bẹni ko si ibiti ẹbọra na fi yatọ si ọba. Fila ori rẹ̀ dabi ade, bata ẹsẹ rẹ̀ dabi bata ẹsẹ awọn alagbara, bẹni ẹwu ọrun rẹ̀ ko yatọ si ti ọba ti o ti gba ade lati ọwọ Oduduwa, ọpọlọpọ awọn iwin miran ni ó tẹle e, ọkan ninu awọn iwin na si gbe apoti kan le ori, o nri ù tẹle e. Igbati gbogbo awa ọdẹ dọbalẹ ti a ki iwin pataki yi, o dahun o nì,...

Wèrédìran ti ngbe ile òmùgọ̀parapọ̀ Ojú-Ìwé 71-75

àtúnṣe

“A kọju si ọna wa, a nlọ, a ko si ri nkankan ju bẹ lọ titi o fi di owurọ ọjọ kan bayi, ni nkan bi agogo mẹwa, ti a ri ọna kan ti o yà baa pa ọtun lọ. A ri akọle yi, o tọka si ọna na: ‘Eleyi ni ilu awọn Alaṣeju nibiti Ọba Alaiyeluwa Aláṣeté ti nṣe ọba wọn.’

“Orukọ ilu yi ko fa ni mọra, ṣugbọn bi ko ti fa ni mọra to yin a, a fẹ lati lọ mọ ibẹ, nitori a le lọ de ibẹ ki a ri ọgbọn diẹ kọ. ...

Igbeyawo Irinkerindo pẹlu aburo olókun iwin inu omi Ojú-Ìwé 76-100

àtúnṣe

“Ṣugbọn kini kan ko ni ṣai ya yin lẹnu nipa emi papa ẹ kò bi mi nkan na dan? On ni wipe lati igbati a ti kuro ni ibiti Ẹlẹgbara ti le wa, ọkan mi ko kuro lara obinrin ti o ṣe itọju mi nigbati Ẹlẹgbara fi le mi kọja oke odò. Gẹ́gẹ́ bi mo ti sọ ṣaju, nko fẹran obinrin ṣaju akoko na, nwọn tilẹ nma rùn si mi ni, nko si mọ ohun ti o fa ti fifẹ ti mo dede wa fẹran obinrin na ju ti itọju mi ti o ṣe nigbana lọ, ṣugbọn ki a má sa fa a gun lọ titi, gongo ori ẹmi mi ni ọmọ na duro le, ọrọ rẹ̀ ki isi ikuro lẹnu mi tobẹ ti o jẹ pe awọn ẹnikeji mi ma nfi mi ṣe yẹ̀yẹ́ ṣa ni....

Ilu itanjẹ-enia Ojú-Ìwé 101-108

àtúnṣe

“Ọpọlọpọ nkan ni a fi oju ri nigbati a kuro ni ilu yi tan ṣugbọn ko si aye nisisiyi lati sọ gbogbo wọn. Sibẹsibẹ na, nko gbọdọ ṣai sọ nkan ti o ṣẹlẹ si mi ni ilu ti a npe ni Itanjẹ-enia.

“Ko si ẹniti o wà ni ode aiye yi ti ko ni agbelebu tireẹ̀ Agbelebu ki isi itilẹ fi ibi nkan rere silẹ. Mo ni agbelebu kan ninu irinajo yi, agbelebu na si ni igba kemi mi, Aiyédèrú-ẹ̀dá. Mo ro pe ẹ o ranti iru ọrọ buruku ti ó sọ niwaju Omugọdimeji ọba ilu awọn Edidarẹ, ẹ o si ṣakiyesi pe ọrọ rẹ̀ kò ju ati fi wa oju Omugọdimeji mọra lọ. ...

Ogun ibode igbo elegbeje Ojú-Ìwé 109-117

àtúnṣe

“Bayi ni ọkunrin na wi, mo si nfẹ ba a sọrọ ki ntúbọ wadi nipa nkan ti o sọ, ṣugbọn, were l’ó kọja, ko duro mọ.

“Igbati o ṣe, a yọ si Igbo Elegbeje. Nkan ti a kọ ṣe akiyesi ni ọwọ̀n nla kan ti ó ba oju ọrun lọ, ti ó duro ni ẹnu ọna igbo na. Igbati ó ba ṣe ti a ba wo oke ọwọ̀n yi, a dabi oju enia. Ti o bat un ṣe, a dabi oju kiniun, igbati ó tun ṣe, a dabi oju ẹkùn. Bi ó ba sit un yi pada a dabi ori ejo nla, a ma yọ ahọn jade bérébéré lẹnu....


  • D.O. Fagunwa (1955), Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje. Nelson Publishers Ltd in association with Evans Brothers (Nigeria Publishers) Ltd; Ìbàdàn, Nigeria. ISBN 978-126-240-0. Ojú-ìwé 117.