Ìsọdàìránmúpè
Ìsọdàìrá́nmúpè ni ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì ní ibi tí ìró aránmúpè yóó ti sọ àbùdá ìránmú rẹ̀ nù tí yóó sì di ìró àìránmúpè. Ìpajẹ àti àrànmọ́ ni ó sábà máa ń fa ìgbésẹ̀ yìí.
Ìsọdàìránmúpè alárànmọ́
àtúnṣeÌgbésẹ̀ yìí má ń wáyé nínú mọ́fíìmù kan. Ẹ jẹ́ kí a wo àpẹẹrẹ
ènìyàn = /ènì᷈ja᷈/ = [èì᷈jà᷈] ==> [èèjà᷈]
esinsin = /esi᷈si᷈/ = [ei᷈sin] ==> [eesi᷈]
egúngún = /egú᷈gú᷈/ = [eú᷈gú᷈] ==> [eégún]
A ó ṣàkíyèsí pé ìpajẹ́ kọ́nsónáǹtì ni ó kọ́kọ́ sẹlẹ̀. Èyí mú kí àwọn fawẹ́lì aránmúpè àti àìrànmúpè fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, lẹ́yìn náà ni fáwẹ́lì àìránmúpè sọ fawẹ́lì aránmúpè di irú ara rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìró àránmúpè sọ ìránmú rẹ̀ nù, tí ó sì di àìránmúpè gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àpẹẹrẹ òkè yìí
Ó tún ṣe é ṣe kí irú ìgbésẹ̀ yìí wáyé láàárín mọ́fíìmù méjì nínú ọ̀rọ̀ bí i:
ọdúnọdún =/ↄdú᷈ↄdú᷈/ =[ↄdↄↄdú᷈]
ọgbọ́nọgbọ́n = /ↄgbↄ᷈ↄgbↄ᷈/ = [ↄgbↄↄgbↄ᷈]
ọ̀kanọ̀kan =/ↄ̴ka᷈ↄkaↄ/ = [ↄkↄↄka᷈]
Ni ibi àwọn àpẹẹrẹ yìí, a ṣàkíyèsí pé, kò sí ìpajẹ kankan bí ó tilẹ̀ wù kó mọ. Ìgbésẹ̀ àrànmọ́ níkan ni ó fà á tí àwọn ìró aránmúpè fi sọ àbùdá ìránmú wọn nù láti di àìránmúpè.
Ìgbésẹ̀ ìsọdàìránmúpè tún lé wáyé lẹ́yìn àwọn ọ̀rọ̀ kan. Ẹ jẹ́ kí a wo àpẹẹrẹ bí i:
rà ú᷈ ==> rà á
tà ú᷈ ==> tà á
kà ú᷈ ==> kà á
ʃe fú᷈ mi = ʃe ú᷈ mi ==> ʃe é mi
jà fú᷈ mi = jà ú᷈ mi ==> jà á mi
Ohun tí ó fojú hàn ni pé, gbogbo ibi tí ìsọdàìránmúpè ti wáyé nínú àpẹẹrẹ òkè yìí ni a ti rí ìfarahàn àrànmọ́.
Ìsọdàìránmúpè onípajẹ
àtúnṣeÌgbésẹ̀ yìí ni ibi tí a ti sọ ìránmú nu nípa ìpàrójẹ. Èyí lè wáyé nínú ẹyọ ọ̀rọ̀ tàbí láàárín àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀.
oní + èdè = elédè
oní + ata = aláta
oní + ɛʤa = ɛlɛ́ʤa
kò yẹ kí á gbàgbé pé ìró aránmúpè [í́] ni a pajẹ nínú àpẹẹrẹ òkè yìí. Ní ìwọ̀n ìgbà tí àrànmú ti kúró ní àgbegbe tí ìró [n] ti jẹyọ, ìró náa yí padà di irú rẹ̀ tí kìí ṣe aránmúpè (ìró [l]). Èyí gan-an sì ni ìsọdàìránmú tí ó wà nínú àwọn àpẹẹrẹ náà. Àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì mìíràn tí ó wáyé láti ni àyọrísí àbájáde òke yìí ni àrànmọ́, ìsóhùnnípò àti ìgbohùnnípò.
Bí a bá tún wo àpẹẹrẹ bí i
fú᷈ olú kɛ́ = f olú kɛ́ ==> fólúkɛ́
fú᷈ olú ʃↄ́ = f olú ʃↄ́ ==> fólúʃↄ́
bù kú᷈ ↄlá = bù k ↄlá ==> bùkↄ́lá
Nínú àpẹẹrẹ yìí, ìgbésẹ̀ ìpajẹ nìkan ni ó wàyé, ìró aránmúpè sì ni a pajẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun orí ìró ti a pajẹ ni a fi ààyè gba lórí ìró mìíràn.
A tún lè wo àpẹẹrẹ bí i:
mú᷈ owó ==> mówó
fú᷈ ewúrɛ́ ==> féwúrɛ́
fú᷈ àgùtà᷈ ==> fágùtà᷈
ìpajẹ ìró aránmú ló mú ìránmú kúrò nínú àwọn ìpèdè òkè yìí.