Ìwà Àjẹbánu jẹ́ abala ìwà àìṣòdodo tàbí ìwà ọ̀daràn tí àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́, àwọn òṣèlú tó wà nípò àṣẹ tàbí agbára máa ń hù fún àǹfàní ara wọn. Ó jẹ́ ìwà ìṣagbáralò fún àǹfàní ara ẹni. Lára àwọn ìwà Àjẹbánu ni Ẹ̀gúnjẹ gbígbà, ìwà ìkówójẹ nípò àṣẹ, ìṣègbè fún ẹ̀bí, ará tàbí ọ̀rẹ́ ẹni fún àǹfàní láìtẹ̀lé ìlànà tàbí òfin.[1] Ìwà Àjẹbánu máa ń ṣẹlẹ̀ ní orísirísi ìwọ̀n. Ó lè wáyé níbi ìṣe kéréje [2] ṣùgbọ́n èyí tí ó bá wáyé láàárín àwọn olóṣèlú tàbí àwọn tó wà nípò àṣẹ jẹ́ èyí tí ó gbajúmọ̀ jùlọ. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó kéré tó, ohun tí kò dára, kò lórúkọ méjì.

A 1902 cartoon depicts a police officer whose eyes are covered with a cloth labelled "bribes",

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Report" (PDF). siteresources.worldbank.org. Archived from the original (PDF) on 5 May 2015. Retrieved 25 September 2012. 
  2. Elliott, Kimberly Ann (1950). "Corruption as an international policy problem: overview and recommendations". Washington, DC: Institute for International Economics. https://piie.com/publications/chapters_preview/12/10ie2334.pdf.