Ìwà ọmọlúàbí
Ìwà Ọmọlúàbí: Ìwà Ọ̀yàyà
Ọ̀yàyà ni ìwà ìdárayá tàbí ìtúraká pẹ̀lú inú dídùn àti ẹ̀rín sí ohun gbogbo tí a bá ń ṣe. Ìwà ọ̀yàyà máa ń hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà nínú ìṣe sí ẹ̀dá. Bí àpẹẹrẹ, ìwà ọ̀yàyà máa ń hàn nínú àṣà ìkíni. A máa ń ṣe èyí nípa kíkí àwọn òbí wa, àwọn tí ó jù wá lọ àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wá. Àṣà ìkíni àti ìdáhùn máa ń wáyé láàárọ̀, lọ́sàn-án, lálẹ́ àti fún onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àsìkò. A lè gbà àlejò kan tí ó wá ènìyàn wá pẹ̀lú ọ̀yàyà. Èyí ni yóò mú kí inú rẹ̀ dùn tí ara rẹ̀ yóò sì yá gágá. Bákan náà, a le fi ọ̀yàyà hàn lẹ́nu iṣẹ́ ẹni. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí ọmọ ilé - ẹ̀kọ́ fi ọ̀yàyà kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní kíláàsì.
Síwájú sí i, a lè fi ọ̀yàyà hàn nínú iṣẹ́ wa ní gbogbo ọ̀nà pàápàá nínú iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ wá. Àǹfààní èyí ni pé gbogbo ohunkóhun tí a bá fi ọ̀yàyà ṣe ni ó máa ń yọrí sí rere.
Ní ìdàkejì, àìní ọ̀yàyà ni à ń pè ní òṣónú tàbí ìwà àìtúraká sí ènìyàn. Ó tún lè jẹ́ àìtúraká sí iṣẹ́ tàbí sí ohùn mìíràn. Ènìyàn tí kò ní ọ̀yàyà kò ṣòro láti mọ̀. Gbogbo ìgbà ni wọn ń rojú kókó. Wọn kì í túra ká sí ènìyàn tàbí sí iṣẹ́ wọn. Wọn kì í sáábà rẹ́rìn-ín. Kò sí ìgbà tí inú wọn ń dùn.
Ẹni tí ó ní ọ̀yàyà máa ń kó ènìyàn mọ́ra. A máa ṣe àlejò pẹ̀lú ara yíyá. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Yorùbá fi máa ń pa á lówe pé: "Ká ríni lókèèrè, ká ṣàríyá, ó yóni, ó ju oúnjẹ lọ. Ọ̀yàyà a máa mú kí ènìyàn ṣe oríire lẹ́nu iṣẹ́. Ó sì tún máa ń jẹ́ kí ènìyàn ní àṣeyọrí nínú ohun gbogbo. Àwọn ènìyàn a sì máa nífẹ̀ẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ láwùjọ.
Ẹni tí kò ní ọ̀yàyà máa ń dáádì káàkiri ní. Àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ a máa jìnnà sí i. Lẹ́nu iṣẹ́, ìgbéga lè jẹ́ ìṣòro fún un. Ní àkórán, Yorùbá kì í ka irú ẹni bẹẹ sí ọmọlúàbí ní àwùjọ.