Ògógóró
Ògógóró jẹ́ ọtí líle ìbílẹ̀ tí wọ́n pọn láti ara ẹmu igi ọ̀pẹ tàbí agbe. Ó jẹ́ ọtí líle ìbílẹ̀ tí wọ́n máa ń mú káàkiri ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà, pàápàá jùlọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ka ethanol sí ògógóró, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Kẹ́míkà ni ethanol, ṣùgbọ́n ògógóró jẹ́ ọtí líle ìbílẹ̀ tí wọ́n pọn láti ara ẹmu igi ọ̀pẹ tàbí agbe.
Àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n ń pe ògógóró
àtúnṣeAkpeteshie lórílẹ̀ èdè Ghana, Omi sapele, pàrágà, kain-kain, Sùn gbalaja, éégún inú ìgò, jẹ́ díè lára àwọn onírúurú orúkọ tí àwọn ènìyàn máa ń pe ògógóró káàkiri ilẹ̀ Yorùbá àti Áfíríkà. Àwọn orúkọ mìíràn tí onírúurú àwọn ènìyàn tún máa ń pè é ní ufofop ní Calabar, rọ́birọ́bi ní Abẹ́òkúta, baba erin Iléṣà, òyìnbó gọ̀, majidun, etonto lédè Àdàmọ̀dì Gẹ̀ẹ́sì, wuru, àwọn Ijaw, Udi Ogagan àti Àdàkọ:Not a typo Bini, Agbagba Urhobo,àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2]