Òjó Adé
Òjó Adé ni wọ́n bí ní (Ojo kewa, Osu Kewa Odun 1959) , Ó jẹ́ olórin, olùkọ orin-ẹ̀mí gósípẹ́ẹ̀lì àti Olùṣọ́ Àgùtàn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]
Ojo Ade | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | October 10, 1959 Ikeji Ile, Ipinle Osun, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1977 - present |
ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bi ní ọjọ́ Kẹ́wàá oṣù Kẹwàá ọdún 1959 (October 10, 1959) ní ìlú Ìkeji-Ilé, ìlú ńlá kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó kẹ́kọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ St. Judges Anglican Church tí ó wà ní Ìkeji-Ilé ṣáájú kí ó tó darí lọ sílùú Èkó fún ìkọ́ṣẹ́ ọwọ́ Electronics. [2]
Ní ọdún 1987, Ó tún tẹ̀ síwájú láti kẹ́kòọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Bíbélì (Calvary International Bible College) lábẹ́ àkóso Olùṣọ́ Àgùtàn Rev. Àńjọọ́rìn, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìwáàsù àti ìhìn-rere ní ìlú Ìbàdàn .[3]
Iṣẹ́ Òòjọ́ rẹ̀
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ ní ọdún 1977 nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ àwọn akorin ìjọ, ṣùgbọ́n tí ó dá ẹgbẹ́ akọrin tirẹ̀ kalẹ̀ ní ọdún 1979. Ní ọdún 1981, tí ó jẹ́ ọdún méjì lẹ́yìn tí ó dá ẹgbẹ́ akọrin ẹ̀mí tirẹ̀ sílẹ̀, ó kọ orin ẹmí kan jáde tí ó sọọ́ di ìlú-mọ̀ọ́ká tí àkọ́lé rẹ ń jẹ́ 'Jésù Tó Fúnmi' , tí ó sì tún gbé òmíràn jáde tí ó tún pè àkọ́lé rẹ̀ ní Sátạ́nì Kò Sinmi. [4]
Ó wà lára àwọn olórin ẹ̀mí ti ìlànà Krìstẹ́nì tí ó ti lààmì-laaka ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pẹ̀lú iṣé takun takun rẹ̀. [5]
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ our reporter. "God Warrior Congress holds programme". The Nation. Retrieved 14 March 2015.
- ↑ Super User. "About Evangelist Ojo Ade". christgiftrevivalministries.org. Archived from the original on 2 April 2015. Retrieved 14 March 2015.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Eloti tV. "Gospel singer lauds Tribune management". elotitv.com. Retrieved 14 March 2015.
- ↑ Akinola Olumide. "Classification of Classification of Nigerian gospel music styles igerian gospel music styles". academia.edu. Archived from the original on 28 December 2014. Retrieved 14 March 2015.