Ṣèyí Ẹdun
Ṣèyí Ẹdun tí àpèjá orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwaṣẹ̀yí Ẹdun tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà ọdún (4th June) jẹ́ gbajúmò òṣèrébìrin sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú Ayétòrò ní Ìpínlẹ̀ ÒGÙN lórílẹ̀-èdè NÀÌJÍRÍÀ. [1]. Òun ni ìyàwó gbajúmọ̀ Òṣerékùnrin Adéníyì Johnson. [2]
Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
àtúnṣeṣèyí Ẹdun jẹ́ ọmọ bíbí Ayétòrò, nílẹ̀ Yewa, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírí nínú ìmọ̀ Olùkọ́ ní Ifáfitì Ọlábísí Ọ̀nàbánjọ ní Ìpínlẹ̀ Ọgùn. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ òun fúnra rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 2008 wọnú 2009,nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tíátà tí wọ́n ń pè ní Wisdom Caucus. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa láti ìgbà náà. [1]
Àtòjọ díẹ̀ nínú àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
àtúnṣe- Ògo Ọlọ́run
- Ẹja ńlá
- Game master
- Dárà
- Four couples
- Ìbídùn Ọlọ́kà
- Irú kan náà
- Ẹni ìtàn
- Wọnúọlá
- Aṣẹ́wó
- Ọkọ ọ̀ mi, ọ̀tá mi
- Ọmọ ọ̀ mi
- Àlè
- Yọ̀mádé
- Oníṣẹ́
- Aláàánú
- Ìyàwó tèmi
- Gbajúmọ̀
- Àmọ̀rí
- Ojifiri
- Amnesia
- Abẹ̀bẹ̀
- Boss lady
- Tùmínínú
- Kútì
- Ex-fiance
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "BIOGRAPHY". OLUWASEYI EDUN. Retrieved 2020-05-22.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Johnson’s, Seyi Edun’s love waxes stronger". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2020-02-28. Retrieved 2020-05-22.