Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò amúlùúdùn ní ilẹ̀ Yorùbá. Jákè jádò ìlẹ Yorùbá la ti ń lù sẹ̀kẹ̀rẹ̀, pàá pàá jùlọ níbí àṣeyẹ oríṣiríṣi.

Drummer ans sekere player

"Sèkèrè" jé òkan. làra oh un tí ó n mú ìdàgbàsókè àti ìdánilárayá wá fún àwon ènìyàn ní àwùjo .Sèkèrè yi jé òkan lára ohun ìlù tí wón n lòní apá ìwò oòrùn nd orílè èdè Nàìjíríà tí a so ìlèkè mó lára igbá tí a sì fi àwòn so ara rè. Sèkèrè jé irinsé ìlù tí ó wópò níìwò oòrùn Áfíríkà àti láàárín àwon aláwò funfun. Nígbàtí a bá n korin ni a máa n mìí.

Orísirísi ònà ni àwon ìlú kankam n pe sèkèrè ìlú Cuba n peé ní "chekere" wón sì tún pèé ní "aggué(abwe). Bákan náà Brazil n pèé ní"xequerê".

Àwọn ìlù akọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lu Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

Kósó: Kósó ni ìlù tí a fi igi ṣe. Awọ la fi ń bo orí igi tí a gbẹ́ náà. O gùn gbọọrọ tó ìwọ̀n ẹṣẹ̀ bàtà méjì àbọ̀. Ó sì tóbi lórí níbí tí a fi awọ bò ju ìsàlẹ̀ lọ, ó ní ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ tí a lè fi gbé e kọ́ apá.[1]

Bẹ́mbẹ́: jẹ́ ìlù tí a fi awọ bo lójú méjèèjì, tí wọ́n sì tún fi awọ tẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí Òkun ṣòkòtò kọ lójú kí ohùn rẹ̀ ó lè dun yàtọ̀ létí. Awọ tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn ṣòkótò yí náà ni wọ́n fi ma ń fà tí wọ́n sì ń fọwọ́ kan ojú ìlù náà kí olè mú Ohun tí onílù náà bá fẹ́ jáde lásìkò tí ó bá ń lùú.[2]

Aro: Ìlù kẹrin tí a ń lù sí sẹ̀kẹ̣̀rẹ̀ ni aro. Irin la fi ń ṣe aro, àwọn alágbẹ̀dẹ ló sì ń ṣe é.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "SEKERE : A MUSICAL INSTRUMENT IN YORUBA LAND WITH INTERNATIONAL APPEAL". Pushnews. 2018-06-20. Archived from the original on 2019-12-30. Retrieved 2019-12-30. 
  2. "Sekere". Adubi Publishing. 2014-05-04. Retrieved 2019-12-30.