Ṣọlá Kòsọ́kọ́
Ṣọlá Kòsọ́kọ́-Abíná (tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù Kínní ọdún born 1976), jẹ́ oṣèrébìnrin àti olùdarí sinimá àgbéléwò ọmọ Yorùbá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jé ọmọ bíbí àgbà òṣèrè Jídé Kòsọ́kọ́. [1]
Ṣọlá Kòsọ́kọ́ | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ṣọlá Kòsọ́kọ́-Abíná ọjọ́ keje oṣù Kínní ọdún 1976 |
Iṣẹ́ | oṣèrébìnrin |
Parent(s) |
|
Ìgbé-ayé Rẹ̀ Ní Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ Kíkà Rẹ̀
àtúnṣeṢọlá Kòsọ́kọ́ jẹ́ ó ọmọbabìnrin Ìsàlẹ̀ Èkó. Ní Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀, ó lọ sí ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ Methodist Primary School, Yaba ní ìpínlè Èkó. Yaba kan náà ló ti kàwé sẹ́kọ́ńdìrì kí ó tó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ifáfitì Olábísí Ọ̀nábánjọ níbi tí ó ti kàwé gboyè nípa ìmò àyíká (sociology). Bí ó tilè jẹ́ pé ìdílé ọba ni Ṣọlá Kòsọ́kọ́ tí wá, bàbá rẹ̀, Jídé Kòsọ́kọ́ jẹ́ gbajúgbajà òṣèrè sinimá àgbéléwò, èyí rán án lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó dára pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà ní kété tí ó parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì kí ó tó di ìlúmọ̀ọ́kà lọ́dún 1999 nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ọmọ Olórííre" Ó gùnlé orúkọ tí bàbá rẹ̀ ti ní pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ bàbá rẹ̀.Ó fẹ́ ọkọ rẹ̀, Abíọ́dún Abíná ní ọdún 2012, wọ́n sì bímọ méjì [2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Sola Kosoko Biography, Age, Marriage, Career, Movies, Net worth, Twitter". Informationcradle. 2017-07-15. Archived from the original on 2019-03-30. Retrieved 2019-10-26.
- ↑ "Sola Kosoko Biography: Age, Husband, Movies & Pictures". 360dopes. 2019-04-14. Retrieved 2019-10-26.