Ṣade Baderinwa
Wọ́n bí Fọláṣadé Ọláyínká Bádérìnwá, tí wọ́n mọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ sí Ṣadé Bádérìnwá (/ˈʃɑːdeɪ ˈbɑːdərɪnwɑː/ /ˈʃɑːdeɪ ˈbɑːdərɪnwɑː/ SHAH-day BAH-dər-in-wah), ní ọjọ́ kẹrìnlá Oṣù kẹ́rin, 1969. (born April 14, 1969) jẹ́ olùdarí ètò ní orí WABC ìkànì kéje (Channel 7). Bákan náà ni ó tún ṣe amúgbá-lẹ́gbẹ́ lórí ètò olósẹ̀-ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú Diana Williams tí ó ma ń wáyé ní dédé agogo márun ìrọ̀lẹ́ (Eyewitness News) àti ìròyìn alágo mọ́kànlá (11.pm news) kan pẹ̀lú Bill Ritter.
Sade Baderinwa | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Folasade Olayinka Baderinwa 14 Oṣù Kẹrin 1969 Baltimore, Maryland |
Iṣẹ́ | Journalist |
Notable credit(s) | Co-anchor of Eyewitness News at 5:00pm for WABC-TV (2003-present) with Diana Williams and the Co-anchor for "Eyewitness News at 11" (2011-present) with Bill Ritter. |
Bàbá rẹ̀ jẹ́ Yor̀ubá ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ German. Orúkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ ni "Fọláṣadé", tó túmọ̀ sí "Someone who uses wealth as crown".[1] Ó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà ti University of Maryland College Park.[2] Lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ ti ja kalẹ̀ láti ọmọdé tí ẹnìkan tí ó jẹ́ African American sì gbàá tọ́ àmọ́ òun àti bàbá rẹ̀ tó ń bẹ ní Nàìjíríà ń sọ̀rọ̀ déédé.[3]
Ṣadé dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ WABC ní ọdún 2003 lẹ́yìn tí ó ṣe díẹ̀ ní ìlú abínibí rẹ̀ Baltimore, Maryland, ní bi tí ó ti darí ètò ìròyìn lórí WBAL-TV fún bí ọdún mẹ́ta. Ṣadé rọ́pò Roz Abrams, tí ó kúrò nílé iṣẹ́ yìí ní ọdún 2003 láti gbaṣẹ́ ní agogo márùún sí mọ́kànĺa alẹ́ (5 and 11 p.m.) ní WCBS-TV.[4] Ní ọjọ́ kẹtàdín-lógún Oṣù kéje, ọdún 2004 (July 23, 2004) nígbà tí ó ń múra láti jábọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé tí ó ṣẹlẹ̀ ní Hackensack, New Jersey , ní ọlọ́kọ̀ kán gba tí ó sì sálọ (hit and run).[5][6][7] Ṣadé padà sídìí iṣẹ́ rẹ̀ (Eyewitness News on December 13, 2004). lẹ́yìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ àti àyẹ̀wò ìgb̀a-dégb̀a, physical therapy,[8]
Bádérìnwá ni ó jẹ́ akéde ètò ọ̀sán tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó gbe lọ sí ìdí ètò ago márùún ìrọ̀lẹ́ (5:p.m) pẹ̀lú Diana Williams. Ṣadé hàn nínú The View gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò lórí October 27, 2006. Bákan náà, ní Oṣù karùún (May, 2011), Bádérìnwá di amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìròyìn alágo mọ́kànlá (11 p.m. news) pẹ̀lú Bill Ritter, tí òun náà sì ń rọ́pò Liz Cho, tí ó kúrò ní ip̀o adarí fún ìwé ìròyìn (new WABC 4 p.m newscast), èyí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lẹ́yìn tí The Oprah Winfrey Show kásẹ̀ kúrò nílẹ̀ tán tí Bádérìnwá sì tẹ̀ síwájú láti ma bá ètò ìròyìn alágo márùn ún 5 p.m. sí 11 p.m. lọ.[9]
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Meaning of Folasade in Nigerian.name
- ↑ Biography at "Sade Baderinwa". WABC-TV. Archived from the original on 2007-02-12. https://web.archive.org/web/20070212045745/http://abclocal.go.com/wabc/story?section=bios&id=3301260. Retrieved 2007-04-08.
- ↑ Stephanie Shapiro (May 12, 2002). "Anchor In Her Life". The Baltimore Sun. Archived from the original on 2011-12-10. https://web.archive.org/web/20111210151731/http://articles.baltimoresun.com/2002-05-12/news/0205130313_1_sade-baderinwa-house-anchor.
- ↑ St. George, Donna (2006-10-31). "A Politician Who Thinks Like a Linebacker". Washington Post. pp. A01. https://www.washingtonpost.com/wp-dyn/content/article/2006/10/30/AR2006103001361.html. Retrieved 2006-12-03.
- ↑ WABC-TV: Sade Baderinwa Update: Cops Hunt Driver, $5,000 Reward Offered Archived 2004-12-31 at the Wayback Machine.
- ↑ Huff, Richard; Hufte, Tom (2004-07-24). "Daily News: TV news anchor struck in hit-and-run". New York Daily News. Archived from the original on 2006-06-29. https://web.archive.org/web/20060629110701/http://www.nydailynews.com/front/story/215341p-185399c.html. Retrieved 2006-12-03.
- ↑ "WBAL-TV: Sade Baderinwa talks about accident that nearly killed her". TheWBALChannel.com. 2005-02-24. Archived from the original on 2006-11-27. https://web.archive.org/web/20061127095454/http://www.thewbalchannel.com/entertainment/4227367/detail.html. Retrieved 2006-12-03.
- ↑ Huff, Richard (2004-12-17). "Ch. 7 anchor's road to recovery". New York Daily News. Archived from the original on 2005-12-27. https://web.archive.org/web/20051227045952/http://www.nydailynews.com/entertainment/story/262757p-224977c.html. Retrieved 2006-12-03.
- ↑ Huff, Richard (2011-04-22). "Inner Tube: Liz Cho, David Novarro to anchor 'Eyewitness News First at 4,' taking 'Oprah' timeslot". New York Daily News. http://www.nydailynews.com/entertainment/tv/2011/04/22/2011-04-22_inner_tube_liz_cho_david_novarro_to_anchor_eyewitness_news_first_at_4_taking_opr.html. Retrieved 2011-04-24.