Ẹ̀KA ÈDÈ YORÙBÁ
A pe ẹ̀ka-èdè ní ‘dialect’ nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe àlàyé pé ọ̀rọ̀ yìí jẹyọ nínú ‘Èdè Gíríkì’ (Greek Language), tí a pè ní ‘Dialecto’, tí ó túmọ̀ sí ọ̀rọ̀-ẹnu, ọ̀nà-ìgbà-báni-sọ̀rọ̀ tàbí ‘àrà ọ̀tọ̀’ nípa ìsọ̀rọ̀. Ẹ̀ka-èdè jẹ́ ìmọ̀ ẹ̀dà-èdè tí ó sọ nípa àwọn ìyàtọ̀ tí ó wà nínú èdè kan nípa bí a ṣe ṣe àtúnpín rẹ̀ sí ìsọ̀rí. Àwọn òǹkọ̀wé Chambers àti Trudgil (1994: 3) pe ẹ̀ka-èdè ní ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ àwọn ará oko, àwọn tí kò rí ọ̀ọ́kán tàbí àwọn tí ó ń dá gbé apá ibìkan tí ó jìnà sí ìlú. A gbà wí pé ẹ̀ka-èdè jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ kan pàtó tí ó jẹ́ ti àwọn ẹ̀yà kan tí wọ́n ń gbé ní agbègbè kan sí àwọn tí ó wà ní ìlú kan.
Ṣùgbọ́n a kò fi ara mọ́ ọ̀rọ̀ bí ‘ará oko’, ‘àwọn tí kò rí ọ̀ọ́kán’ Ìdí ni pé àwọn tí ó ń sọ èdè àjùmọ̀lò (standard variety), ẹ̀ka-èdè náà ni àwọn onímọ̀ gbà pé wọ́n ń sọ. Olúmúyíwá (1994: 2) sọ pé ẹ̀ka-èdè jẹ́ ọ̀kan lára èdè àjùmọ̀lò àwọn ẹ̀yà kan tí okùn èdè so pọ̀. Awóbùlúyì́ (1981: 1) sọ pé ẹ̀ka-èdè jẹ́ ẹ̀yà-èdè kan tí wọ́n ń sọ ní àwùjọ kan tí irú àwùjọ ènìyàn bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àwùjọ ńlá mìíràn tí èdè kan papọ̀. Ẹ jẹ́ kí á di àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí mú – ‘ẹ̀dà-èdè’ àti ‘ẹ̀yà-èdè’.
Adéníyì àti Òjó (2005: 25) ṣe àpèjúwe ẹ̀ka-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dà-èdè ńlá kan tàbí ọ̀nà ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ tí àwọn àdúgbò tàbí agbègbè kan ń ṣe àmúlò rẹ̀ láti fi gbé èrò ọkàn wọn jáde lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí ti agbègbè mìíràn tí gbogbo wọn wà ní ẹkùn kan náà, ṣùgbọ́n tí àwọn ará agbègbè méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ yìí gbọ́ ara wọn ní àgbọ́yé.
Síwájú síi, ẹ̀dà-èdè ti àdúgbò kọ̀ọ̀kan ń sọ yìí ní àwọn àbùdá ètò ìró (fọnọ́lọ́jì), ìhun gírámà àti pípe ọ̀rọ̀ tí ó yàtọ̀ sí ti ẹ̀ka mìíràn. Àwọn òǹkọ̀wé yìí ṣe àlàyé pé: Èdè kédè tí àwọn tí ó ń sọ ọ́ bá pọ̀ díẹ̀, tí wọ́n sì takété sí ara wọn gbọ́dọ̀ ní ẹ̀ka, pàápàá jùlọ tí omi kíkún, igbó dídí tàbí òkè ńlá bá là wọ́n láàárín.