Alhaji Lukman Ẹ̀bùn Olóyèdé Ọláìyá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Igwe jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti òṣèré sinimá àgbéléwò. Wọ́n bí Ẹ̀bùn Olóyèdé ní ilú Kẹ́nta, Òkè-Èjìgbò Abẹ́òkúta.

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ọláìyá lọ sí ilé ìwé alákọ̀ọ́bọẹ̀rẹ̀ St.Judes ní ìlú Abẹ́òkútaìpínlẹ̀ Ògùn, tí ó sì tún tè síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé girama (Premier) ní Abẹ́òkúta. Lẹ́yìn tí ó parí èyí ni ó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbára ẹni sọọ̀rọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe tí Moshood Abíọ́lá Òjéèrè ìpínlẹ̀ Ògùn.

Iṣẹ́ rè gẹ́gẹ́ bí òṣèré

àtúnṣe

Ọláìyá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré Musibau Shodimú ní àsìkò ọdún 1970s tí ó wà ní Abẹ́òkúta nígbà náà.[1]

Àwon ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Olaiya Igwe (Lukmon Ebun Oloyede) Biography". LoudestGist Wikipedia. 2016-06-09. Archived from the original on 2018-11-01. Retrieved 2018-11-01.